Konilegbele ipinlẹ Eko ti di aago mẹfa aarọ si mewaa ale.

Aderohunmu Kazeem

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti tun ṣe atunṣe si asiko ti awọn eeyan ipinlẹ naa yoo lanfaani lati maa lo nita pẹlu bo ṣe kede pe awọn araalu le wa nigboro lati aago mefa aarọ di mẹwaa alẹ, yatọ si aago mefa aarọ si mẹjọ alẹ to ti wa atẹlẹ.

Kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ naa, Gbenga Ọmọtọṣọ, lo kede eleyii.  O ni lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu kẹwaa yii, awọn ara ipinle Eko ni anfaani lati maa jade lati aago mẹfa aarọ si aago mẹwaa alẹ lọ sibi ti wọn ba fẹ.

Sanwo-Olu waa dupe lọwọ awọn ara Eko fun ifọwọsowọpọ wọn lati ri i pe alaafia jọba nipinle naa. Bakan naa lo ni ki wọn yago fun ohunkohun to le ṣakoba fun alaafia ipinlẹ naa.

Leave a Reply