Kootu ju Sani sẹwọn oṣu mẹta, ẹni to ṣoniduuro fun lo sa lọ

Adewale Adeoye

Ko sẹni to ri baba agbalagba kan, Sani Ukasha, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn to n laagun yọbọ, to si n rawọ ẹbẹ si adajọ agba ileejọ ‘Area Court’ kan, Onidaajọ Shawomi Bokkos, ti aanu rẹ ko ni i ṣe e.

Oju aanu lo ko ba baba agbalagba naa, ẹni kan lo ṣoniduuro fun, niyẹn ba sa lọ ko too di ọjọ igbẹjọ.

Ninu alaye Olupẹjọ, Insipẹkitọ Gokwat Ibrahim, to foju ọdaran naa bale-ẹjọ nigba ti igbẹjọ rẹ maa kọkọ waye sọ pe ṣe lo lọọ ji awọn ohun eelo isebẹ lọdọ oniṣowo kan, ti ọwọ si pada tẹ ẹ. Iwa yii ni agbefọba ni o lodi sofin iwa ọdaran ti ipinlẹ naa n lo, o si ni ijiya ninu pẹlu.

Nigba ti ọdaran naa ko rẹni gidi kan to le ṣe oniduuro fun un ni Ọgbẹni Sani ba gba lati duro fun un ki wọn le gba beeli rẹ lọjọ naa. Ṣugbọn nigba ti igbẹjọ rẹ maa fi waye laipẹ yii, ọdaran naa ti sa lọ.

Insipẹkitọ Ibrahim ni nitori pe ọdaran naa mọ pe oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an lo ṣe sa lọ, lati le ma jiya ẹṣẹ ohun to ṣe.

Loju-ẹsẹ ni Sani to ṣe oniduuro fun ọdaran naa ti n rawọ ẹbẹ si adajọ pe ko ṣiju aanu wo ọun nipa ọrọ naa, ati pe laye oun, oun ko tun ni i jẹ ṣe oniduuro fun ẹnikẹni mọ rara.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ agba kootu naa, Onidaajọ Shawomi Bokkos, ni ki Sani lọọ ṣewọn oṣu mẹta gbako ninu ọgba ẹwọn kan to wa lagbegbe naa, tabi ko san ẹgbẹrun mẹwaa Naira gẹgẹ bii owo itanra fun ijiya ẹṣẹ to ṣẹ.

 

Leave a Reply