Korona yoo dohun igbagbe nilẹ wa laipẹ – Ọọni Ogunwusi

Florence Babaṣọla

Ọọni ti Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja 11, ti sọ asọtẹlẹ pe igba diẹ lo ku fun ajakalẹ arun Koronafairọọsi lati di ohun igbagbe lorileede Naijiria.

Lasiko ti awọn Ọlọṣun (Osun devotees) ṣabẹwo si i laafin rẹ layaajọ ọdun Ọṣun ni Ọọni sọrọ idaniloju yii.

Ogunwusi sọ pe ko si ariyanjiyan kankan ninu ẹ rara, arun Korona wa nilẹ wa, o si n ja kaakiri bii oro lojoojumọ, o waa ku si ọwọ ẹnikọọkan lati ṣọra ṣe laarin ilu.

Kabiesi ṣalaye pe idi ti awọn ko fi ṣe ọdun Ọṣun naa lalariwo bi wọn ṣe maa n ṣe e tẹlẹ n’Ileefẹ ni lati ma ṣe faaye gba itankalẹ arun naa.

O ni asiko ọdun Ọṣun jẹ asiko lati ṣayẹyẹ omi, omi si ṣe pataki ninu igbesi aye ẹda. Arole Oodua lo asiko naa lati gbadura pe ki Ẹlẹdaa fi omi wẹ gbogbo aye mọ kuro ninu laluri ajakalẹ arun Korona.

Ọba Ogunwusi bu ẹnu atẹ lu awọn ti wọn maa n pe awọn Ọlọṣun ni abọriṣa, o ni iranti awọn alalẹ ni wọn n ṣe, iwulo omi ko si ṣee fọwọ rọ sẹyin lawujọ wa.

Nibi ayẹyẹ.naa, Arabinrin Ṣọla Duro-Ladipọ lati ileeṣẹ to n ri si ọrọ aṣa ati ibudo igbafẹ nipinlẹ Ọṣun lo ṣoju gomina, o si ṣeleri pe gbogbo ọdun to jẹ ti aṣa nijọba yoo maa gbaruku ti.

Leave a Reply