Koronafairọọsi pa ọga agba kan nileewe Yaba Tech

Jide Alabi

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii nileewe gíga Yaba Tech, l’Ekoo, paṣẹ pe ki gbogbo awọn akẹkọọ fi ileewe naa silẹ pẹlu bi wọn ṣe kede pe àrùn koronafairọọsi ti pa ọkan lara awọn ọga agba níbẹ̀.
Ọgbẹni M.A.O Omoighe.
Loju-ẹsẹ ti iṣẹlẹ ọhun waye ni wọn ti kede ki wọn  ti ẹka ti olóògbé yìí ti jẹ adari pa fun ọsẹ meji, bẹẹ ni wọn tun sọ pe ki awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ lọọ ṣayẹwo ara wọn, ki wọn si para mọ titi ti wọn yóò fi ri aridaju pe wọn kò ní arun ọhun lara.
Ṣiwaju si i, awọn alaṣẹ ileewe naa ti sọ pe ki awọn omọleewe maa gba ikẹkọọ wọn lori ayelujara, ati pe gbogbo ipade to ba ti ju eeyan mẹ́wàá lọ, ori ẹrọ ayelujara ni ki iru ẹ ti máa wáyé.

Leave a Reply