Kwara: Wọn ti ọsibitu ile ijọba pa nitori iku Aminu Logun

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Nitori ẹru pe o ṣee ṣe ki olori oṣiṣẹ lọfiisi gomina, Oloogbe Aminu Logun, ti ko arun Koronafairọọsi ran awọn oṣiṣẹ to wa nileewosan ile ijọba, ijọba ti gbe ibẹ ti pa.

ALAROYE hu u gbọ pe ileewosan naa ni wọn kọkọ gbe Logun lọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nigba to n ṣaarẹ, lati ọfiisi rẹ gan-an ni wọn si ti ru u lọ sibẹ.

Wọn ni lẹyin tawọn oṣiṣẹ ilera to wa lọsibitu naa ri i pe kinni ọhun n lagbara ju bo ṣe yẹ ni wọn ni ki wọn gbe e lọ sileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin. Ọjọ keji, Tusidee, ni Logun jade laye.

Latigba ti ayẹwo ti fi han pe arun Korona lọkunrin naa ni nidaamu ti de ba awọn oṣiṣẹ ilera to wa nile ijọba. Idi niyi tijọba fi tete gbe ileewosan naa ti pa lati ma jẹ ki arun naa tan kiri.

Leave a Reply