Labẹ ijọba Buhari yii, afaimọ ki dẹmokiresi ma pokunso– Ṣoyinka

Faith Adebọla, Eko

Gbajugbaja onkọwe nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti la ọrọ mọlẹ pe ti Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, ba ṣi n kọ eti ọgbọnyin si bawọn eeyan lọtun-un losi ṣe n pariwo pe kijọba apapọ ji giri, ki wọn si wa nnkan gidi ṣe lati yanju ọrọ aabo to dojuru yii, afaimọ ni orileede yii yoo fi le roju raaye ṣe ajọdun ayẹyẹ demokiresi ti wọn n pe ni “Democracy Day” lọdun to n bọ.

Wọle Ṣoyinka sọrọ yii nigba to n dahun ibeere ninu ifọrọwanilẹnuwo kan tileeṣẹ tẹlifiṣan aladaani Arise ṣe fun un lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ọjọgbọn naa kilọ pe oun ko ri bi orileede yii ko ṣe ni i fọ si wẹwẹ ti Aarẹ ko ba tete gbe igbesẹ lati din aṣẹ apapọ ku, kawọn ipinlẹ ati ijọba ibilẹ le maa yanju ọrọ wọn labẹle wọn.

Bayii ni Ṣoyinka ṣe ṣalaye ọrọ ọhun, o ni:

“Lọri ọrọ ijọba awa-ara-wa ti wọn n pe ni demokiresi yii, niṣe la fẹẹ pin eto naa lẹmi-in bi nnkan ṣe n lọ yii, tabi ki n kuku sọ ọ lọrọ mi-in, demokiresi ti fẹẹ pokun so nilẹ wa bayii. Buhari gbọdọ la eti rẹ silẹ lati gbọ awọn ariwo to n lọ lọtun-un losi ati layiika ijọba rẹ bayii, ko si gbe igbesẹ pato lori ẹ.

“Buhari gbọdọ mọ pe bi orileede yii ṣe n sare lọ soko ipinya ti pọ si i lẹnu ọjọ mẹta yii ju ti atẹyinwa lọ, koda o ju ti igba ti a jagun abẹle lọ pẹlu, mi o si ro pe orileede yii le wa lodidi ti a o ba tete ṣe nnkan lori dindin agbara ati aṣẹ apapọ ku.

“Ti Naijiria ko ba tete ṣe bẹẹ ni kiamọsa paapaa, kawọn eeyan si ri i pe loootọ ni iyatọ ti wa, a jẹ pe Naijiria ko le wa lodidi niyẹn o. Ti orileede kan ba n lọ soko iparun, tẹmi ti fẹẹ bọ lẹnu ẹ, awọn ti wọn ba ri iru nnkan bẹẹ ti wọn o si fẹ ki ajalu ọhun ṣakoba fun wọn le kigbe sita pe ‘ẹ dakun o, awa o ba baaluu yii lọ mọ o, a fẹẹ bọọlẹ o.

O ti waa ye mi bayii pe ero ọtọọtọ ati itumọ oriṣiiriṣii lawọn eeyan ni nipa demokiresi, paapaa awọn oloṣelu to n dari wa, o si n jọ mi loju pe boya ni ijọba yii mọ ohun ti wọn n sọ lẹnu ati ohun to tumọ si ni ti gidi nigba ti wọn ba n sọ pe awọn n ṣejọba demokiresi, mi o ro pe wọn mọ ojuṣe to rọ mọ ọn.”

Bakan naa ni Ọjọgbọn Soyinka sọ pe bijọba ṣe n fọwọ dẹngẹrẹ mu aroye tawọn eeyan n ṣe nipa ọrọ aabo ati awọn nnkan to n jẹ wọn niya kaakiri ilẹ yii fihan pe ijọba apapọ ti o ṣetan lati feti silẹ lo wa lori aleefa.

O ni: “Gbogbo bijọba ṣe n fofin de tibi, ti wọn n gbẹsẹ le tọhun yii, to si jẹ awọn eto ibanisọrọ tawọn eeyan le fi kegbajare, ti wọn le fi sọ ẹdun ọkan wọn sita, ni wọn n fofin de wọnyi, niṣe ni wọn tubọ n fọ opo to gbe eto ijọba dẹmokiresi duro si wẹwẹ. Ki i ṣe keeyan kan sọ ọjọ kejila, oṣu kẹfa, lorukọ demokiresi lo fihan pe tọhun mọ ohun tijọba awa-ara-wa tumọ si.

Awọn ede ti Buhari n pe lati fesi si bawọn eeyan ṣe n pariwo pe awọn fẹẹ pinya ko daa, ko daa rara ni. Olori to ba larojinlẹ gbọdọ ronu, ko si loye, idi tawọn eeyan fi n pariwo, ti wọn si fi fẹẹ yapa, idi yẹn lo yẹn ko fun lafiyesi, ko si ṣiṣẹ le e lori, ki i ṣe lati bẹrẹ si i dun kuku-laja tabi halẹ mọ wọn, ki i ṣe lati kan maa sọrọ idẹruba rara.”

Lori ọrọ fifi maaluu jẹko, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ni awọn gomina wa ti n fi ọrọ falẹ ju, ojo ni wọn, igba ti ina ba jo dori koko nikan ni wọn maa too sọrọ, bẹẹ ohun tawọn eeyan wọn fẹ lo yẹ ki wọn ṣiṣẹ le lori, ki i ṣe ti Abuja.

“Fun apẹẹrẹ, awọn gomina iha Guusu ilẹ wa sọrọ lorukọ awọn eeyan ipinlẹ wọn gbogbo, wọn lawọn o fẹ fifi ẹran jẹko ni gbangba mọ kaakiri ipinlẹ awọn. Ẹnikan waa jokoo sile agbara ni Aso Rọọki, o loun maa sọ fun minisita feto idajọ ati amofin agba lati lọọ hu ofin amunisin aye ọjọun kan jade, koun le gba awọn ilẹ kaakiri awọn ipinlẹ fun okoowo aladaani ọsin maaluu, ẹ o ri i pe niṣe niyẹn fihan pe ọrọ tawọn araalu atawọn gomina to ṣoju fun wọn n sọ ko wọ wọn leti.

O ti to asiko to yẹ k’Aarẹ le gbogbo awọn to yi i ka danu, o yẹ ko gbe iwe ‘iṣẹ tan’ le wọn lọwọ ni, tori wọn o ṣe Aarẹ funra ẹ ati Naijiria loore kan, ohun ti Aarẹ fẹẹ gbọ ni wọn n sọ fun un, bo si ṣe n gbara le ọrọ ati amọran wọn, niṣe niṣakoso ẹ tubọ n lọ gọọ-gọọ sinu ọgbun.

‘‘Ni ti awọn Fulani agbebọn, awọn ajinigbe ati afẹmiṣofo wọnyi, lakọọkọ, o yẹ ki Buhari ba araalu sọrọ. Ki i ṣe ọrọ bii ifọrọwanilẹnuwo to ṣe lori tẹlifiṣan kọja yii to ti n sọ pe ara oun le koko, ṣaka lara oun da o, iyẹn kọ la n sọ. O gbọdọ sọrọ bii akin, ko si kede pe oju ogun la wa, ka le mura ija silẹ daadaa. O gbọdọ bẹrẹ si i sọrọ bo ṣe yẹ kolori to mọ ohun to n ṣẹlẹ ṣe maa sọrọ. Ọrọ aabo to dojuru yii ti kọja ihalẹ lasan, o ti di ohun ti a gbọdọ gbe igbesẹ gidi lori ẹ.

Bakan naa ni Ṣoyinka di ẹbi ru awọn aṣofin ijọba apapọ, o ni: Awọn aṣofin wa o ṣe daadaa rara, wọn o ṣeto pẹlu, paapaa awọn aṣoju-sofin ati awọn aṣofin agba. Ta a ba wo inu iwe ofin ilẹ wa daadaa, a maa ri i pe awọn agbara ati aṣẹ kan wa ti wọn ni to yẹ ki wọn lo lati gun ijọba apapọ yii ni kẹṣẹ, lati le wọn sare, ṣugbọn wọn kọ, wọn ko lo o, iyẹn si jẹ ki gbogbo nnkan dẹnu kọlẹ dipo ko tẹsiwaju.

Awọn araalu n gbiyanju o, wọn n bọ sigboro, sawọn opopona gbogbo lati fi ẹhonu han, lati fi aidunnu wọn han. Ijọba gbọdọ mọ pe ọrọ ti kọja ihalẹ mọni ati idẹruba ni, awọn eeyan ko fẹẹ gbọ iru awọn ihalẹ mọ ni bẹẹ yẹn mọ, ko si si olori to le tẹ ifẹ ọkan  wọn mọlẹ ti wọn ba ṣetan. Ijọba gbọdọ tẹti si wọn ni.

Leave a Reply