L’Abẹokuta, Ṣeyi ta mọto ti wọn ni ko tunṣe, lo ba fowo gbọ bukaata ara ẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Ọkunrin mẹkaniiki kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ṣeyi Ọrẹbajo, ni kootu Majisreeti ilu Abẹokuta ti ran lẹwọn oṣu mẹta bayii, nitori wọn lo ta mọto ti wọn ni ko tunṣe, o si fowo ọkọ naa gbọ bukaata ara tiẹ.

Ọgbẹni Samuel Solomon lo ni mọto naa gẹgẹ bi Agbefọba, ASP Ọlakunle Shọnibarẹ, ṣe ṣalaye.  O ni logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020, ni Ṣeyi ta mọto Honda naa ti iye rẹ to ẹgbẹrun lọna igba ataabọ naira (250,000). Agbegbe Obada, niluu Abẹokuta, lo ti huwa naa.

Agbefọba sọ ọ di mimọ pe nigba ti Ṣeyi ko ri mọto da pada fun ẹni to ni in, iyẹn fi ọlọpaa mu un. O ni olujẹjọ gba lati sanwo ọkọ naa pada, o si san ẹgbẹrun lọna ogun naira ninu ẹ, ṣugbọn ko ri omi-in san mọ latigba to ti san ti akọkọ.

Nigba ti ọrọ naa de kootu lo foju han pe Ṣeyi ti kọkọ gba ẹgbẹrun mẹwaa naira owo iṣẹ lọwọ Solomon, kaka ko si ṣiṣẹ ọhun, niṣe lo gbe mọto ta, eyi to lodi sofin ijọba, to si ta ko iwa ọmọluabi pẹlu.

Abala irinwo din mẹwaa, ipin kẹsan-an (390) (9) lo ta ko ẹsun ti Ṣeyi n jẹjọ ẹ yii ninu iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ogun ti wọn se lọdun 2006.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ, olujẹjọ loun ko jẹbi. Ṣugbọn Adajọ Abilekọ M.O Ṣomẹfun sọ pe gbogbo ẹri lo foju han pe iwa ole ni Ṣeyi Ọrẹbajo hu, o si jẹbi ẹsun ti ile-ẹjọ fi kan an.

Sibẹ naa, adajọ fun un lanfaani lati san ẹgbẹrun mẹwaa owo iṣẹ to gba lọwọ Solomon, ko si san ẹgbẹrun lọna igba ati ọgbọn naira to ṣẹku ninu owo mọto yii, ko fi ṣe itanran ọran to da.

Ṣugbọn Ṣeyi ko ri ẹgbẹrun mẹwaa naa san debi ti yoo tilẹ san ẹgbẹrun lọna igba ati ọgbọn, bi wọn ṣe gbe e lọ sọgba ẹwọn Ibara, niluu Abẹokuta, niyẹn.

 

Leave a Reply