Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii, to tun jẹ gomina nipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti sọ pẹlu idaniloju pe ẹni to jẹ akọwe funjọba nigba to wa ni gomina, Alhaji Moshood Adeoti, ni yoo di gomina ipinlẹ Ọṣun loṣu Keje, ọdun yii.
Latigba diẹ sẹyin ni wahala ti wa laarin Arẹgbẹṣọla ati Gomina Gboyega Oyetọla, bi awọn ọmọlẹyin Arẹgbẹṣọla ṣe n pe ara wọn ni TOP naa ni awọn ti Oyetọla pe ara wọn ni IleriOluwa.
Ọmọọba Gboyega Famọdun ni awọn IleriOluwa gba gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, nigba ti awọn TOP ri Alhaji Rasaq Ṣalinṣile gẹgẹ bii alaga.
Awọn IleriOluwa fọwọ si i pe ki Oyetọla lọ fun saa keji lori aleefa, nigba ti Alhaji Moshood Adeoti gba fọọmu lati igun awọn TOP pe oun naa fẹẹ dupo gomina, opin ọsẹ yii ni wọn yoo si dibo abẹle lati mu oludije wọn.
Lọjọ Aje, Mọnde, nibi ipade ẹgbẹ APC ti ẹkun idibo Oriade/Obokun, eleyii to waye ninu ọgba ileetura Zenabab, niluu Ijẹbu-Jeṣa, ni Arẹgbẹṣọla ti sọ pe ko si ibaṣepọ kankan mọ laarin oun ati Oyetọla, nitori gomina naa ti pa ilana ẹgbẹ oṣelu APC da.
O ke sawọn ọmọ ẹgbẹ naa lati fi imọ ṣọkan, ki wọn ma ṣe bẹru ẹnikẹni, ṣugbọn ki wọn jade lati dibo wọn fun Adeoti ninu ibo abẹle to n bọ lọna, ki wọn si ri i pe Adeoti di gomina.
Arẹgbẹṣọla ṣalaye siwaju pe “Ẹnikẹni to ba wa pẹlu wa nigba ti a bẹrẹ irinnajo lati gba ipinlẹ Ọṣun lọdun 2004 yoo mọ pe ija nla la ja ka too ni iṣẹgun ti a ni loni-in yii. A koju ọpọ ipenina, a si bori, lasiko yii naa, a maa bori.
“A ti ṣetan lati faaye gba ilana ijọba tiwa-n-tiwa nitootọ. Awa yatọ si awọn ti wọn sọ ara wọn di Ọlọrun kekere. A ti pinnu lati gba ẹgbẹ wa lọwọ awọn ti wọn lero pe awọn yoo ba awọn iṣẹ rere ti a ti ṣe silẹ jẹ.
“Mo fẹẹ fi da yin loju pe Ọlọrun wa pẹlu wa. Mo rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati ma ṣe bẹru rara. Awa ni ojulowo ẹgbẹ APC l’Ọṣun. To ba jẹ pe wọn ko faaye gba gomina ti ko ṣe daadaa nipinlẹ Eko lati lọ fun saa keji, ki lo de ti ko le ṣẹlẹ bẹẹ l’Ọṣun. Wọn mọ pe nnkan ti awọn ṣe si wa ko dara, wọn si fẹẹ tẹ siwaju ninu ẹ. A ko ni i gba fun wọn.
“Ẹ ma bẹru ihalẹ wọn. Ẹ jade waa dibo fun oludije wa. in Shaa Allah, Adeoti ni gomina to n bọ nipinlẹ Ọṣun. Ẹ jẹ ka fọwọ sowọpọ pẹlu ẹ.”
Ninu ọrọ rẹ, Alhaji Moshood Adeoti dupẹ lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC fun atilẹyin wọn, o si ṣeleri pe oun ko ni i ja wọn kulẹ, oun yoo si ṣiṣẹ lori itẹsiwaju awọn igbesẹ amuyangan ti ẹgbẹ naa ṣe silẹ laarin oṣu Kọkanla, ọdun 2010, si oṣu Kọkanla, ọdun 2018.
Lara awọn ti wọn wa nibi eto naa ni Alhaji Rasaq Adeoti, Ọnarebu Najeem Salam, Alagba Lọwọ Adebiyi ati awọn oloye TOP kaakiri ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun.