Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Kaakiri awọn ipinlẹ to wa lorileede yii lawọn eeyan ti tu yaaya wọnu ilu Oṣogbo lọjọ kẹtala, oṣu kẹjọ, ti i ṣe ọjọ Ẹti, fun ayẹyẹ aṣekagba ọdun Ọṣun Oṣogbo ti wọn maa n ṣe lọdọọdun.
Pẹlu bijọba ipinlẹ Ọṣun ṣe kede pe iwọnba eeyan perete ni ki wọn wa, ati pe ki awọn ti wọn ko gbe nitosi maa wo eto naa lori ẹrọ ayelujara, sibẹ, odo Ọṣun ko gba ero.
Ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu kẹjọ, ọdun yii, leto naa bẹrẹ pẹlu ìwọpópó, titan atupa oloju-mẹrindinlogun lo si tẹ le e.
Ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹjọ, ni ayẹyẹ Ibọriade, nibi ti wọn ti tẹ gbogbo ade awọn Ataọja to ti kọja lọ silẹ fun iwure niwaju Ataọja, Arugba, Yeye Ọṣun ati gbogbo awọn ti wọn ni ipa lati ko lori ọrọ ọdun Ọṣun Oṣogbo.
Lati Ọjọbọ, Tọsidee, ti aṣekagba ti ku ọla ni oniruuru awọn eeyan ti n wọnu ipinlẹ Ọṣun, paapaa, awọn olubọ Ọṣun jake-jado Naijiria lati fi oju gan-an-ni odo naa.
Bo ṣe di bii aago meje aarọ ọjọ Ẹti ni wọn ti bẹrẹ si i wọ lọ si ojubọ odo Ọṣun to wa ni Isalẹ-Ọṣun, niluu Oṣogbo. Aṣọ funfun ni ọpọlọpọ awọn ti wọn wa nibẹ wọ, bẹẹ ni awọn ọlọja bii ike-omi, ilẹkẹ, ọti ati bẹẹ bẹẹ lọ n taja wọn wẹlẹwẹlẹ.
Ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ni arugba de pẹlu Yeye Ọṣun atawọn iya aṣa, bo si ṣe n kọja lọ si odo lawọn eeyan n beere oniruuru nnkan lọwọ rẹ.
Ninu ọrọ Araba Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, o ke si gbogbo ọmọ Yoruba lati mọ pe aṣa ati iṣe wọn ṣe koko, ki wọn dẹkun hihu iwa oniwa nile ati lẹyin odi.
O ni ki iran Yoruba wa ọna lati maa daabo bo ara wọn ati aṣa ti wọn gbe dani, ki wọn ma ṣe faaye gba ẹsin okeere lati gba iṣẹṣe lọwọ wọn.