Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Lẹyin ti kọmiṣanna ọlọpaa Ogun tẹlẹ, Edward Awolọwọ Ajogun, fẹyinti layaajọ Ominira Naijiria to kọja, ipinlẹ naa ti ni kọmiṣanna tuntun bayii, orukọ rẹ ni Lanre Sikiru Bankọle.
Gẹgẹ bi atẹjiṣẹ to kede kọmiṣanna ọlọpaa tuntun yii, eyi ti wọn kọ lọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 ṣe wi, wọn ni ki ọga ọlọpaa tuntun naa bẹrẹ iṣẹ lẹyẹ-o-ṣọka nipinlẹ Ogun ni.
Ki wọn too gbe CP Bankọle wa sipinlẹ Ogun yii, Eko lo wa gẹgẹ bii kọmiṣanna fun ọlọpaa agbaaye (INTERPOL, FCID).