Lasiko ọdun Keresi, Buhari ṣeleri igba daadaa fawọn ọmọ Naijiria

Faith Adebọla

Aarẹ orileede yii, Muhammadu Buhari ti bẹ gbogbo ọmọ orileede yii lati ma ṣe sọreti nu ninu agbara iṣakoso oun lati mu igba ọtun ti wọn n reti wa.

Ninu iṣẹ ikini ọdun Keresimesi ti Aarẹ Buhari ran si awọn ọmọ Naijiria lo ti sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. O ni oun mọ bi nnkan ṣe ri lasiko yii fun gbogbo ọmọ orileede yii.

O ni asiko ayọ, alaafia, ireti, ifẹ ati inuure lasiko Keresi maa n jẹ, paapaa fawọn ọmọlẹyin Kristi, ṣugbọn awọn iṣoro ijinigbe, janduku, ọrọ-aje to n ṣojojo, arun Korona atawọn nnkan mi-in ko jẹ ki pọpọṣinṣin naa ri bo ṣe yẹ ko ri.

Buhari ni tori eyi loun ṣe n fi asiko yii rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ orileede yii lati ma ṣe sọreti nu, o ni iṣoro aabo torileede yii n koju kọja awọn erongba ati aba tawọn eeyan n sọ kaakiri, ati pe lẹnu aisun, aiwo, lawọn ileeṣẹ ologun ilẹ wa atawọn agbofinro mi-in wa lati koju ipenija aabo to mẹhẹ naa.

O bẹ awọn araalu lati rọju si i, ki wọn si tubọ fun awọn agbofinro ati ileeṣẹ ologun laaye ati atilẹyin, ki wọn le koju iṣoro ohun titi ti wọn yoo fi ṣaṣeyọri.

Buhari ni afi toun ba fẹẹ purọ lo ku, oun gba pe ọkan lara olori ojuṣe oun gẹgẹ bii Aarẹ ni lati jẹ ki eto aabo fun gbogbo araalu fẹsẹ rinlẹ, oun o si ni i sinmi titi ti eyi yoo fi ri bẹẹ.

 

Leave a Reply