Faith Adebọla, Eko
Bi ki ibaa ṣe ti awọn ọlọpaa tẹsan Bariga to rin sasiko, oṣiṣẹ ijọba Eko, ẹni ọdun marunlelọgọta ti wọn porukọ ẹ ni Akinlolu Ajayi, iba ti para ẹ. ALAROYE gbọ pe lasiko to fẹẹ bẹ sinu alagbalugbu omi ọsa lori biriiji Afara Kẹta, l’Ekoo, ni wọn ti gan-an lapa.
CSP Adekunle Ajiṣebutu to fọrọ yii ṣọwọ s’ALAROYE sọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, niṣẹlẹ naa waye, ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ owurọ.
O ni oṣiṣẹ ijọba lọkunrin to fẹẹ gbẹmi ara ẹ yii, ileeṣẹ to n mojuto awọn dukia ijọba Eko, LSDPC, ni ọna Town Planning, Ilupeju, lo n ba ṣiṣẹ, ṣugbọn Opopona Owodunni, lagbegbe Oworonshoki, ni wọn lo n gbe.
Wọn ni bọkunrin naa ṣe n gun irin ti wọn ṣe seti odo naa lawọn ọlọpaa ikọ to n gbogun ti idigunjale n kọja lọ ninu ọkọ patiroolu wọn, ni wọn ba ri i, ti wọn si sare lọọ mu un ko too bẹ somi ọhun. Wọn lọkunrin naa jẹwọ pe oun fẹẹ para oun ni, tori aye ti su oun.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe kawọn agbofinro lẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran kan sawọn mọlẹbi afurasi yii, ki wọn si ṣewadii ohun to pin in lẹmi-in to fi fẹẹ gbe iru igbesẹ buruku bẹẹ.
O ni abọ iwadii lo maa pinnu boya ọkunrin naa maa foju bale-ẹjọ, tori iwa ọdaran ni keeyan gbẹmi ara ẹ.