Lasiko ti wọn fẹẹ gbowo itusilẹ, ẹṣọ alaabo mu awọn ajinigbe meji balẹ ni Kwara   

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin 

Ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ifọwọsowọpọ ẹgbẹ fijilante, ni Kwara, ti doola ẹmi iya atọmọ ẹ, Afusat Lawal ati Taofeek Lawal, ti awọn ajinigbe ji gbe lagbegbe Shao, nijọba ibilẹ Moro. Lasiko ti wọn fẹẹ gba wọn silẹ naa ni wọn mu ajinigbe meji balẹ, wọn si ri mọto ayọkẹlẹ Honda kan gba lọwọ wọn.

 

Tẹ o ba gbagbe, awọn agbebọn ọhun lo ya bo ile-igbe oludije dupo ileegbimọ aṣofin ninu ẹgbẹ oselu APC ni Kwara, lẹkun idibo Malete/ Ipayẹ/Oloru, Họnarebu  Lawal Ayansọla Saliu, ti wọn si ji iyawo ati ọmọ ẹ, Afusat ati Taofeek, gbe lọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lopopona Oke-Ayẹwu /Shao.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ifọwọsowọpọ ẹgbẹ fijilante ti doola ẹmi iya atọmọ rẹ layọ ati alaafia, ti wọn si ti darapọ mọ mọlẹbi wọn.

O tẹsiwaju pe lasiko ti awọn ajinigbe naa fẹẹ gba owo itusilẹ ni awọn ẹṣọ alaabo ati awọn ajinigbe doju ibọn kọra wọn, ti ibọn si n ro lakọ-lakọ. Wọn mu meji balẹ ninu wọn, awọn to ku si sa lọ. Wọn gbe awọn mejeeji lọ si ileewosan, ṣugbọn ọkan pada ku, ti wọn si ri mọto ayọkẹlẹ Họnda kan gba lọwọ wọn.

Leave a Reply