Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lori akọlu tawọn Fulani darandaran n ṣe sawọn eeyan agbegbe kan nipinlẹ Ondo, Gomina Rotimi Akeredolu ti bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ gbogbo awọn ọba alaye.
Arọwa yii waye lasiko ti Alauga ti Auga Akoko, Ọba Samuel Agunloye atawọn ijoye kan ṣabẹwo si ọfiisi rẹ ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Arakunrin ni ko ṣee ṣe ki oun laju silẹ kì awọn ọdaran tabi awọn agbesummọmi kan ti wọn n pe ara wọn ni Fulani darandaran maa ṣe bo ti wu wọn nibikibi nipinlẹ Ondo.
Gomina ni bi awọn awọn darandaran ọhun ṣe n ṣe akọlu, ti wọn si fẹẹ sọ ara wọn di ẹrujẹjẹ fawọn agbẹ ati oko wọn lawọn ilu to wa lẹnu ibode ipinlẹ Ondo n fẹ amojuto kiakia.
Aketi ni gbogbo ipa to wa ni ikawọ oun loun yoo sa lati ri i daju pe ọwọ tẹ awọn janduku agbebọn ọhun laipẹ, ki wọn le waa foju wina ofin.
O fi kun un pe ijọba ti n ṣeto lati ko ọgọọrọ awọn ẹṣọ alaabo lọ sawọn agbegbe ti wọn n ṣe akọlu si. O rọ awọn ọba atawọn adari agbegbe kọọkan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu Amọtẹkun atawọn ẹṣọ alaabo mi-in fun alaafia ipinlẹ Ondo lapapọ.