Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọgọọrọ awọn ọdọ ilu Akoko ni wọn jade lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lati fẹhonu han ta ko bi ẹmi awọn eeyan ṣe n sọnu ninu ijamba ọkọ to n waye lemọ lemọ lagbegbe naa.
Ọpọlọpọ wakati lawọn olufẹhonu naa fi di gbogbo ọna to wọ ilu Akungba ati Iwarọ Ọka Akoko pa, lai fun ẹnikẹni ninu awọn arinrin-ajo to fẹẹ gba oju ọna marosẹ ọhun laaye lati kọja.
Ibinu lawọn ọdọ naa fi le awọn aṣoju gomina ipinlẹ Ondo ti Amofin Tunji Abayọmi ko sodi lati ṣabẹwo si ibi ti ijamba naa ti waye lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja pada.
Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Bọlaji Salami, nikan ni wọn faaye gba ko gbe ọkọ rẹ kọja, gbogbo ọkọ awọn akọwọọrin rẹ to tẹle e ni wọn da pada.
Gbogbo arọwa tí Kọmiṣanna feto ọgbin nipinlẹ naa, Gboyega Adefarati, pa fawọn ọdọ tinu n bi ọhun ko jọ bii ẹni wọ wọn leti rara, ohun ti wọn n ṣaa n tẹnumọ ni pe awọn ko fẹẹ ri awọn aṣoju Gomina Akeredolu ṣoju, wọn ni oun funra rẹ lawọn fẹ ko waa ba awọn sọrọ.
Iṣẹlẹ yii lo mu kawọn alasẹ Fasiti naa tete kede titi ileewe ọhun pa lẹyẹ-o-ṣọka.
Wọn ni awọn fun gbogbo awọn akẹkọọ naa di aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ki olukuluku wọn fi pada sile rẹ.