Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Latari ipenija eto aabo to n koju ipinlẹ naa lọwọ lọwọ, Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti ṣeleri lati gba awọn eeyan to kunju oṣuwọn kun awọn ẹsọ Amọtẹkun.
Arakunrin sọrọ yii lasiko tawọn eeyan ilu Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ, waa ki i lọfiisi rẹ to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.
Isoro eto aabo tawọn eeyan ipinlẹ Ondo n koju lo ni o tubọ n buru si i latari awọn nnkan ija oloro tawọn janduku ji ko ninu rogbodiyan to suyọ lasiko iwọde SARS to waye losu bii meji sẹyin.
O ni lati igba tawọn agbebọn tí da ẹmi Olufọn tilu Ifọn, Ọba Israel Adeusi, legbodo lawọn ẹsọ Amọtẹkun ko ti sinmi pẹlu bí wọn ṣe n fi igba gbogbo rìn kaakiri inu awọn aginju to wa lagbegbe ijọba ibilẹ Ọsẹ, ki wọn le foju awọn onisẹẹbi naa han.
Gomina ọhun ni ijọba ti n gbe igbesẹ lati peṣe awọn nnkan ija to yẹ fawọn Amọtẹkun, ko baa le rọrun fun wọn lati doju ija kọ awọn ọdaran to n yọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo lẹnu.