Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lati nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC ti dibo yan awọn oloye tuntun ti yoo maa tukọ ẹgbẹ naa kaakiri orilẹ-ede yii ni nnkan ko ti rọgbọ mọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun nijọba Ifẹdọrẹ, nipinlẹ Ondo, latari ọkan-o-jọkan ẹsun magomago ti wọn lo waye lasiko eto naa.
Nibi tọrọ naa bi awọn eeyan kan ninu de, aarin ọsẹ ta a wa yii ni wọn mori le ile-ẹjọ giga kan niluu Akurẹ lati lọọ pẹjọ ta ko alaga afun-n-ṣọ ẹgbẹ naa, Gomina Mai Mala Buni, alaga igbimọ to mojuto eto ọhun to tun jẹ gomina ipinlẹ Ọṣun, Alaaji Gboyega Oyetọla, alaga ẹgbẹ nipinlẹ Ondo, Ade Adetimẹhin, Tunde Fawoyi ati ajọ eleto idibo.
Awọn tinu n bi ọhun, ninu eyi ti ọmọ ileegbimọ asofin nigba kan ri, Ọnarebu Idowu Pius Adebusuyi ati Ọgbẹni Sẹgun Bọbọi wa, ni ki ile-ẹjọ fagi le eto idibo naa nitori pe awọn to ṣeto rẹ kuna lati tẹle ofin ati ilana ẹgbẹ APC.
Pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ ni wọn ni wọn ko fun lanfaani ati kopa rara ninu eto naa, ati pe ṣe ni wọn fi tipatipa fa awọn oloye ati aṣoju ẹgbẹ tuntun ti wọn yan le awọn lori nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ.
Oriṣiiriṣii oko ọrọ lawọn ọmọ ẹgbẹ naa fi n kan ara wọn lati ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja lọhun-un, ti eto naa ti waye, tawọn mi-in si n fẹsun kan Olori ile-igbimọ aṣofin Ondo, Ọnarebu Bamidele Ọlẹyẹlogun, to jẹ ọmọ bibi ilu Iṣarun, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, ati Ade Adetimẹhin pe awọn lo wa nidii gbogbo rukerudo to n waye lọwọ.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn eeyan ọhun kọkọ ko ara wọn jọ niluu Igbara-Oke to jẹ ibujokoo ijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ lati fẹhonu han lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ti wọn ko gbọ nnkan kan lati ọdọ awọn aṣaaju ẹgbẹ l’Abuja, ohun to bi awọn eeyan ọhun ninu ree ti wọn fi lọọ pẹjọ ta ko gbogbo igbesẹ to waye lasiko eto naa.