Faith Adebọla
Dandan lowo-ori, ọran-an-yan laṣọ ibora, nijọba apapọ sọ ọrọ gbigba abẹrẹ ajẹsara arun Koronafairọọsi di fawọn oṣiṣẹ ọba, paapaa awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ, wọn ti fun wọn ni gbedeke ọjọ ki-in-ni, oṣu kejila, ọdun yii, lati lọọ gbabẹrẹ naa, aijẹ bẹẹ, wọn o ni i le wọle sọfiisi wọn lati ọjọ naa lọ.
Alaga igbimọ akanṣe tileeṣẹ Aarẹ gbe kale lati ṣe kokaari amojuto arun Korona nilẹ wa, to tun jẹ Akọwe fun ijọba apapọ, Ọgbẹni Boss Mustapha, lo sọrọ yii l’Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee yii.
Lasiko to n sọrọ nibi ipade atigbadegba ti wọn maa n ṣe lati ṣalaye ibi ti ọrọ arun Korona de duro nilẹ wa, Mustapha ni:
“Bẹrẹ lati ọjọ ki-in-ni, oṣu Disẹmba, ọdun 2021, awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ gbọdọ maa ṣafihan iwe-ẹri pe awọn ti gbabẹrẹ ajẹsara arun Korona, tabi iwe-ẹri pe wọn ti lọọ ṣayẹwo, wọn o si ni arun naa lara, ayẹwo naa si gbọdọ jẹ eyi ti wọn ṣe laarin wakati mejilelaaadọrin (ọjọ mẹta) ki wọn too le gba wọn laaye lati wọ awọn ọfiisi wọn gbogbo, ateyi to wa l’Abuja, atawọn ọfiisi ijọba apapọ to wa kaakiri awọn ipinlẹ mi-in lorileede yii.”
Mustapha tun ṣalaye pe gbedeke naa kan awọn oṣiṣẹ ọba lọfiisi awọn aṣoju Naijiria lawọn ilẹ okeere pẹlu. O lawọn maa kọ lẹta kan lati faṣẹ si gbedeke naa kaakiri ọfiisi awọn oṣiṣẹ ọba laipẹ.
Mustapha sọ pe akiyesi ati iṣiro tawọn onimọ nipa arun ṣe kari aye fihan pe lẹnu lọọlọọ yii, arun Korona ti n lọ silẹ, ọpọ orileede ni iṣiro naa sọ pe wọn ti n kapa arun ọhun, awọn to n lugbadi rẹ tabi ti arun naa n ṣeku pa ko lọ soke bii ti tẹlẹ mọ, o n dinku si i ni.
O lawọn arinrinajo lati Naijiria lọ sorileede United Kingdom ti lominira si i, tori awọn alaṣẹ UK ti gba lati fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn ba ti gbabẹrẹ Korona lati Naijiria laaye lati maa ba irinajo wọn lọ.