Abdulsalam dero ẹwọn Kirikiri l’Ekoo, wọn ni ole paraku ni

Faith Adebọla, Eko

Gbogbo ẹbẹ afurasi ọdaran ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Abdulsalam Muktar, pe ki wọn jẹ koun maa ti ile waa jẹ ẹjọ ole jija ti wọn fi kan an l’Adajọ J. A. Oyegun tile-ẹjọ Majisreeti Ikẹja, nipinlẹ Eko, da nu bii omi iṣanwọ, o ni ọgba ẹwọn Kirikiri ni ko ti lọọ maa gbatẹgun titi dọjọ igbẹjọ to kan.

Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni wọn wọ ọkunrin naa dele-ẹjọ Majisreeti ọhun, ẹsun ole jija, dida omi alaafia ilu ru ati lilo nnkan ija oloro lati huwa ibi ni wọn fi kan an.

Agbefọba, ASP Benson Emuerhi, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjo kejidinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni afurasi ọdaran yii huwa idigunjale ọhun, oun ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ kan ni wọn n da awọn eeyan lọna ni ikorita Dorba, lagbegbe Festac, ijọba ibilẹ Amuwo-Ọdọfin, nipinlẹ Eko, kọwọ awọn agbofinro too tẹ ẹ.

Benson ni awọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku ti sa lọ, ṣugbọn awọn agbofinro ṣi n wa wọn loju mejeeji.

O lawọn ka ibọn kan ati ọbẹ aṣooro mọ afurasi ọdaran yii lọwọ, iwadii tawọn ọlọpaa si ṣe fihan pe firi-nidii-ọkẹ, alọkolohun-kigbe pọnbele ni, iwa to si hu ta ko isọri kẹtadinlọọọdunrin (297) ati ikọkandinlọọọdunrun (299) iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Eko.

Abdusalam loun ko jẹbi, o si bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn ṣaanu oun, ki wọn yọnda beeli foun, ki oun le maa ti ile waa jẹjọ, ṣugbọn Adajọ Adegun ni ko sọrọ ninu ibeere rẹ, o ni ki wọn fi faili ẹsun rẹ ṣọwọ sọdọ ajọ DPP fun amọran wọn, ki wọn si mu afurasi naa pamọ sọgba ẹwọn Kirikiri, titi di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.

Leave a Reply