Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni yii, gẹgẹ bii aaye isinmi lẹnu iṣẹ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ki wọn le lanfaani ati lọọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn lọwọ ajọ eleto idibo.
Ikede yii waye ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin Gomina, Richard Ọlatunde, fi sita ṣọwọ sawọn oniroyin laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.
Ninu atẹjade ọhun ni Gomina Akeredolu ti parọwa sawọn oṣiṣẹ yala nileesẹ ijọba tabi ti aladaani, awọn oniṣẹ ọwọ pẹlu gbogbo awọn tọjọ ori wọn ti to mejidinlogun lati lo anfaani aaye isinmi tijọba kede rẹ lọọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn lọfiisi ajọ eleto idibo to wa nijọba ibilẹ wọn tabi nibikibi to ba sun mọ wọn.
Eyi nikan lo ni yoo fun awọn eeyan loore-ọfẹ lati le ṣe ojuṣe wọn ki wọn si dibo yan ẹnikẹni to ba wu wọn ninu eto idibo gbogbogboo to n bọ lọna, o ni kaadi idibo yii ni iwe-aṣẹ ati agbara ti awọn eeyan ni lati mu nnkan bọ sipo si bi wọn ṣe n fẹ ni Naijiria.
Aketi waa paṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ igbimọ aṣejọba rẹ atawọn ti wọn di ipo kan tabi omiran mu labẹ iṣakoso rẹ ki wọn pada si ilu ati ijọba ibilẹ olukuluku wọn ki wọn le mojuto bi awọn eeyan wọn ṣe n gba kaadi idibo.