Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti kede pe oun yoo bẹrẹ ipade ẹlẹẹkan loṣu mẹrin kaakiri ẹkun idibo mesẹẹsan to wa nipinlẹ Ọṣun, lati le jẹ kawọn araalu mọ nnkan to n lọ ninu iṣejọba oun loorekoore.
Ipade naa, to pe ni ‘Ipade Imọlẹ’, ni yoo bẹrẹ nipari oṣu Kẹfa, ọdun yii.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun gomina, Mallam Ọlawale Rasheed, ṣe sọ ninu atẹjade kan, o ni ninu ipade naa ni gomina yoo ti maa ṣalaye lẹkun-unrẹrẹ nipa iṣẹ tijọba ba dawọ le, ati owo ti wọn fẹẹ na le e lori.
O ni ko si iṣẹ akanṣe kankan tijọba gbe jade ti gomina ko ni i ṣalaye owo to jade pẹlu rẹ ati awọn agbegbe ti wọn fẹẹ gbe awọn iṣẹ akanṣe naa lọ.
Ọlawale sọ siwaju pe ‘Ipade Imọlẹ’ yoo fun awọn araalu lanfaani lati beere ibeere lọwọ gomina, ati lati sọ ibi ti wọn ba ti n reti ọwọja iṣejọba Adeleke.
A oo ranti pe lasiko ti Oloye Bisi Akande jẹ gomina ipinlẹ Ọṣun ni wọn bẹrẹ iru ipade bayii, orukọ ti wọn pe e nigba naa ni ‘Labẹ Ọdan’. Ṣe ni wọn maa n lọ lati ijọba ibilẹ kan si omi-in nigba naa.
Lasiko iṣejọba Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, ‘Gbagede Ọrọ’ ni wọn pe orukọ rẹ, inu ọgba ile igbohunsafẹfẹ OSBC, niluu Oṣogbo, ni wọn awọn araalu ti maa n waa pade gomina.
Lasiko Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ‘Ogbeni Till Day Break’ ni wọn pe e, oru ni wọn si maa n ṣepade naa, nibi ti awọn araalu yoo ti pejọ sinu gbọngan nla ti wọn ba fẹẹ lo.
Nigba to di asiko Alhaji Gboyega Oyetọla, ‘Apero’ ni wọn pe iru ipade yii, ṣugbọn ẹẹkan pere ni wọn ṣe e titi ti ọdun mẹrin rẹ fi pe, inu gbọngan nla kan niluu Ikirun, ni wọn si ti ṣe e lọsan-an ọjọ naa.
Ni bayii, ‘Ipade Imọlẹ’ ni Gomina Adeleke pe tiẹ, o ni gbogbo awọn araalu ni yoo mọ pe akoyawọ wa ninu iṣejọba oun.