Lati Port Harcourt ni Rita ti waa fawọn ọmọbinrin mẹrin ṣiṣẹ aṣẹwo n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ ẹṣọ alaabo sifu difẹnsi, ẹka tipinlẹ Kwara, ti mu arabinrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan, Gift Rita, fẹsun pe o ko awọn ọdọbinrin mẹrin kan ti wọn o darukọ wọn wa siluu Ilọrin, lati Port Harcourt, fun iṣẹ aṣẹwo.
Adari ajọ sifu difẹnsi ni Kwara, Ọgbẹni Makinde Iskil Ayinla, lo fi ọrọ naa lede fawọn oniroyin niluu Ilọrin, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. O ni ọwọ tẹ arabinrin kan, Gift Rita, to n fi awọn ọmọdebinrin tọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹẹẹdogun si mẹrindinlogun ṣe iṣẹ aṣẹwo, sugbọn awọn eeyan kan to mọ nipa ohun to fẹẹ ṣe yii lo ta ajọ naa lolobo tọwọ fi tẹ ẹ.

Afọlabi tẹsiwaju pe lẹyin ti awọn mu Rita tan, awọn ti ko awọn ọmọde naa lọ sọdọ ajọ to n ri si iwa ifọmọ-ṣẹru nipinlẹ Kwara (NAPTIP), ti wọn si fa wọn le adari ajọ ọhun, Saadu Mustapha, lọwọ fun ẹkunrẹrẹ iwadii.
Wọn ni Rita yoo foju bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply