Pẹlu ibinu lawọn eeyan fi n sọrọ si Oludamọran fun eto iroyin fun Aarẹ orilẹ-ede yii, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, lori ọrọ to sọ laipẹ yii pe niṣe lo yẹ ki awọn ọmọ Naijiria maa dupẹ ti bọmbu ko maa dun leralera lọsọọsẹ mọ, ṣugbọn to n waye lẹẹkọọkan bayii.
Lori tẹlifiṣan kan niluu Eko ni ọkunrin oniroyin yii ti sọrọ yii lasiko to n fesi si bi eto aabo ṣe mẹhẹ bayii, paapaa nigba to n fesi si bi wọn tun ṣe paayan nibi marun-un ọtọotọ laarin ọjọ meloo kan sẹyin.
Adeṣina sọ pe nigba kan ri, ojoojumọ ni bọmbu maa n dun, ninu eyi ti ọpọ ẹmi ti maa ṣofo, ti bọmbu mẹfa le dun laarin ọjọ kan ṣoṣo.
O ni latigba ti Aarẹ Muhammed Buhari ti wa nipo ni wahala awọn Boko Haram ti lọ silẹ daadaa ni Naijiria, ti awọn janduku afẹmiṣofo yii ki i raaye ju bọmbu deede mọ, to jẹ pe ẹẹkan bayii laarin oṣu mẹta ni wọn n ju u.
Bi ọkunrin naa ṣe sọrọ yii tan lawọn eeyan ti gba a mọ ọn lẹnu, ti wọn si sọ pe dajudaju, ijẹkujẹ ti oun naa ti n ri jẹ ninu ijọba Buhari ni ko jẹ ko le sọ otitọ mọ.
Adeṣina sọ pe ni bayii, laarin ọpọlọpọ ọsẹ ati oṣu, eeyan le maa gburoo pe wọn ju bọmbu nibi kan, eyi tiru ẹ ki i waye tẹlẹ ki Buhari too di Aarẹ, ati pe niṣe lo yẹ ki awọn ọmọ Naijiria maa dupẹ ti iṣẹlẹ pe oun ki i ṣe ojojumọ mọ