Ọwọ tẹ Rasaki ati Wasiu nibi ti wọn ti n ja awọn onimọto lole lori biriiji Ọtẹdọla

Faith Adebọla, Eko

Ọwọ ọlọpaa ikọ ayaraṣaṣa,  Rapid Response Squad (RRS) ti tẹ awọn afurasi ẹlẹgbẹ okunkun meji kan ti wọn fẹsun kan pe wọn n da awọn onimọto ati ero laamu lori biriiji Ọtẹdọla, loju ọna marosẹ Eko si Ibadan, nipinlẹ Eko.

Awọn mejeeji tọwọ ba lọjọ Abamẹta to kọja yii ni Rasaki Babatunde, ẹni ọdun mẹjilelogun, to niṣẹ mẹkaniiki loun n ṣe, ati Idowu Wasiu, ọmọ ọdun mẹrindinlogun, telọ loun pera ẹ.

Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi, ṣe sọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE, o ni ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ni wọn ri awọn mejeeji yii mu, ṣugbọn wọn ju meji lọ, awọn yooku ti sa lọ ni.

Adejọbi ni ọkada kan to ni nọmba NND 268 WZ ni wọn gbe wa, wọn ba ibọn iṣere ọmọde kan ati awọn nnkan ija bii ọbẹ ati aake lara wọn.

Wọn ni nigba ti wọn ṣewadii laṣiiri tu pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Awawa bọis’ ni wọn, agbegbe Isọ-Koko, l’Agege, ni wọn n gbe, ibẹ si ni wọn jẹwọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to ku wa.

Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn mejeeji si ẹka ọtẹlẹmuyẹ, o lawọn ti n fimu finlẹ, iwadii si ti n lọ ni pẹrẹu lati ri awọn to sa lọ atawọn ẹlẹgbẹ okunkun yooku mu, ki wọn le fi wọn jofin.

Leave a Reply