Fulani darandaran, fijilante ati ikọ Amọtẹkun kọ lu ara wọn niluu Kọmu

Olu-Theo Omolohun Oke-Ogun

Ilu Kọmu, nijọba ibilẹ Itẹsiwaju, nipinlẹ Ọyọ, ni wahala ti waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, lakooko ti ikọ Amọtẹkun fẹẹ gba awọn ohun ija oloro tawọn Fulani darandaran kan lagbegbe ọhun saaba maa n ko kiri, eyi ti wọn ni wọn ko gbọdọ wọnu ọja ilu naa pẹlu awọn nnkan ija bẹẹ.

Gegẹ bi ẹni tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣe ṣalaye f’ALAROYE,  o ni pẹ tawọn araalu naa ti maa n kọ fawọn Fulani yii pe wọn ko gbọdọ wọnu ibi ti ero pọ si pẹlu awọn nnkan ija ọhun, ṣugbọn nigba mi-in, wọn maa n rufin naa.

Eyi lo mu kawọn ikọ Amọtẹkun ti wọn wa lẹnubode ati awọn ọja gbegi dina fun wọn lọjọ naa.

Wọn ni nigba tawọn Fulani de ọdọ awọn Amọtẹkun yii ti wọn yẹ ara wọn wo, wọn ri awọn nnkan ija bii ida oloju meji, ọbẹ aṣooro atawọn oogun abẹnu gọngọ mi-in. Ni wọn ba gba a silẹ lọwọ wọn pe ki wọn waa gba a pada ti wọn ba ti na ọja tan.

Eyi ni wọn ni ko tẹ awọn Fulani naa lọrun, wọn lawọn o le fi nnkan agbara awọn silẹ, bẹẹ lawọn o le ṣe kawọn ma na ọja, bọrọ ṣe di ariyanjiyan ree.

Nibi ti wọn ti n fa ọrọ yii lọwọ lawọn Fulani ẹgbẹ wọn mi-in ti de, ti wọn si kọju ija si ikọ Amọtẹkun.

ALAROYE gbọ pe lakooko wahala naa ni ọkan lara ọmọ ẹgbẹ fijilante (VGN) igun ti

Sunday Ọlajide lati ilu Ọyọ bẹrẹ si i ba ọkan lara ẹṣọ Amọtẹkun ja, ti Fulani naa si fẹsun kan an pe ẹgbẹrun lọna igba naira (N200,000) ti sọnu lọwọ oun, afi ki awọn Amọtẹkun ba oun wa a lawari. Ọkunrin Fijilante ọhun la gbọ pe o mu Fulani yii lọọ fẹjọ sun lagọọ ọlọpaa pe awọn Amọtẹkun ti ja owo gba lọwọ oun.

Ẹsun ole jija yii la gbọ pe o bi awọn Amọtẹkun ti wọn ṣẹṣẹ pari idanilẹkọọ wọn ninu ti wọn fi tutọ soke foju gba a pe ohun to ba gba lawọn yoo fun un lati ṣawari owo ti wọn lo poora ọhun ati pe awọn ti ṣetan lati lo ọgbọn ibilẹ foju asebajẹ han laarin wọn. Ibẹ ni wọn fori ọrọ naa ti si di bayii.

Onirọ ti ilu Kọmu, Ọba Jonah Ọlagboyega, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti gbe igbimọ kan dide ti yoo ri si bi alaafia yoo ṣe jọba laarin ilu. O ni lara awọn ipinnu ti wọn ṣe ni pe ko gbọdọ si Fulani tuntun mi-in niluu naa yatọ sawọn ti wọn ti wa nibẹ tẹlẹ, tawọn to si wa nibẹ tẹlẹ naa gbọdọ kọwọ bọwe adehun alaafia.

Leave a Reply