Layaajọ ọdun Keresi, ere asapajude fẹmi eeyan mẹta ṣofo l’Ogun

Gbenga Amos, Ogun

 Eeyan mẹta, ti wọn ri ibẹrẹ ayajọ ọdun Keresi to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2022, ko pari ọjọ naa ti wọn fi jade laye. Ijamba bọọsi akero kan ti wọn wa ninu rẹ, eyi to waye nitosi biriiji Kara, lọna marosẹ Eko s’Ibadan lo da ẹmi wọn legbodo, eeyan mẹfa mi-in la gbọ pe wọn fara pa yanna-yanna ninu iṣẹlẹ ọhun.

Alukoro ati adari eto iroyin fawọn ẹṣọ alaabo oju popo, Federal Road Safety Commission, ẹka ti ipinlẹ Ogun, Abilekọ Florence Okpe, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe ere asapajude lo ṣokunfa ijamba ọhun.

O ni bọọsi akero Toyota Hiace kan ti nọmba rẹ jẹ AYB 88 YP ati ọkọ akẹru kan ti ko ni nọmba ni wọn jọ kọ lu ara wọn.

Wọn ni niṣe ni bọọsi to n ba ere buruku bọ naa fẹẹ ya ọkọ akẹru ọhun silẹ, o ni koun kọja lẹgbẹẹ rẹ ni, ṣugbọn ko ri i ṣe, niṣe lo kọ lu ọkọ akẹru naa latẹyin, lo ba gbokiti. Florence ni loju-ẹsẹ ni mẹta ninu awọn ero mejidinlogun to wa ninu bọọsi naa ti doloogbe.

Pẹlu iranlọwọ awọn eeyan to wa nitosi, atawọn ẹlẹyinju-aanu ni wọn ṣaajo awọn ero naa, ati isapa awọn ẹṣọ alaabo Road Safety, ni wọn fi ri eeyan mẹfa yọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ti ṣeṣe gidigidi, aṣọ wọn si ti rin gbindin fun ẹjẹ, o lẹsẹkẹsẹ lawọn ti ko wọn lọ sileewosan aladaani Famous, fun itọju pajawiri.

O lawọn ti ko oku awọn mẹta naa lọ si ileegboku-si ọsibitu Idẹra, to wa ni Ṣagamu, nipinlẹ Ogun.

Amọ ori ko awọn mọkanla kan yọ, o ni golo-ginni tadiẹ n toko emọ bọ lọrọ tiwọn, wọn o fara pa, ẹsẹ ara wọn si ni wọn fi rin jade ninu ọkọ ọhun.

Bakan naa lo lawọn ti wọ awoku ọkọ naa kuro laarin ọna, ko maa baa ṣediwọ fun lilọ-bibọ ọkọ ni marosẹ ọhun.

Ọga agba ajọ Road Safety nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar, sọ pe ijamba yii ki ba ti waye ka ni dẹrẹba naa fẹsọ wakọ, tawọn ero si tun tete ki i nilọ nigba to bẹrẹ ere buruku naa, amọ abamọ ki i ṣaaju ọrọ, ẹyin lo n wa.

Umar waa rọ awọn onimọto lati ṣe pẹlẹ loju popo lasiko pọpọ ṣinṣin ọdun yii.

Leave a Reply