Lẹyin ọjọ mọkanla, Fayẹmi bọ lọwọ Korona

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Lẹyin ọjọ mọkanla ti Gomina Kayọde Fayẹmi tipinlẹ Ekiti ti ni arun Koronafairọọsi, o ti kede pe oun ti ri iwosan bayii.

Fayẹmi lo kede esi ayẹwo to fi han pe o ni arun naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, to lọ lọhun-un, to si gbe awọn aṣẹ iṣejọba le igbakeji rẹ, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi, lọwọ.

Laaarọ yii lo kọ ọrọ sori ikanni ayelujara Twitter rẹ pe, ”Lẹyin ọjọ mọkanla ti mo ti wa ni igbele, mo gba iroyin pe ayewo ti mo ṣe nigba keji fi han pe mi o ni arun naa mọ.

“Mo dupẹ pupọ lọwọ Ọlọrun, mọlẹbi mi, awọn onimọ iṣegun to tọju mi atawọn ololufẹ mi fun adura ati aduroti.

“Gbogbo nnkan ta a ba le ṣe lati dena arun yii la oo ṣe.”

Leave a Reply