Faith Adebọla, Eko
Ikawọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, lagbegbe Yaba, nipinlẹ Eko, lawọn gende meji yii, Samson Tella, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, ati Rapheal John, ẹni ọdun mọkanlelogun, wa bayii. Ole ni wọn ja, mọto sọọlẹ ni wọn fi n lu jibiti lagbegbe Lẹkki, kọwọ too ba wọn.
Ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ yii, niṣẹlẹ to ko wọn si yọọyọọ yii waye, niṣe ni wọn da onimọto kan to n fi ọkọ Toyota Corolla rẹ ṣe kabukabu lagbegbe Ikate, duro, wọn ni ko gbe awọn lọ sọna Isalẹ Eko.
Ko pẹ ti wọn wọ mọto naa, a gbọ pe bi wọn ṣe n lọ lọna, niṣe ni wọn bẹrẹ si i lọ siarin (steering) mọ dẹrẹba lọwọ, ni wọn ba gba ọkọ naa lọwọ ẹ, wọn si wa a lọ si adugbo kan nikọja Ikate, wọn ni ki dẹrẹba naa fi kaadi ipọwo ATM ẹ gbowo jade ninu akaunti fawọn, wọn si gba ẹgbẹrun lọna ogun lọwọ ẹ. Ikate naa ni wọn fi onimọto ọhun si, lawọn ba ṣina sọkọ, wọn sa lọ.
Bi wọn ṣe n lọ ni dẹrẹba naa figbe bọnu pe awọn ole to gba mọto oun ni wọn n lọ yẹn, Ọlọrun si ba a ṣe, awọn ọlọpaa lati teṣan Ilasan wa nitosi, nibi tawọn ti n ṣe patiroolu wọn.
Awọn ni wọn bẹrẹ si i tọpa wọn lọ, wọn o ri wọn lọjọ naa tori ilẹ ti ṣu, aajin ti jin. Ọjọ keji ni wọn ka awọn mejeeji mọ pẹlu mọto onimọto ti wọn ja gba, ṣọọbu mẹkaniiki kan to wa lagbegbe Lafiaji, l’Erekuṣu Eko lọhun-un, ni wọn ti ri wọn, funfun balau ni ọda ara ọkọ naa, nọmba rẹ ni Lagos JJJ 242 FW.
Ṣa, wọn fi pampẹ ofin gbe wọn, wọn si ti taari wọn sawọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti. Wọn lawọn afurasi naa jẹwọ pe ole lawọn n ja onimọto atawọn ero to n wọkọ sọọlẹ lagbegbe naa, wọn ni “one chance” lawọn n ṣe lagbegbe Lẹkki si Ajah.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti sọ lati ẹnu Alukoro wọn, Olumuyiwa Adejọbi, pe awọn maa foju awọn afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ tiwadii ba ti pari.