Lẹyin ipade tawọn gomina to n ṣakoso lorukọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ṣe laarin ara wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu keji yii, ati ipade ti wọn ṣe pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari lọjọ keji, Tusidee, ọjọ kejilelogun, wọn ti fẹnu ko lati yan agbegbe ti wọn maa pin awọn ipo alakooso apapọ ẹgbẹ APC si lasiko apero gbogbogboo ẹgbẹ naa to maa waye loṣu to n bọ.
Bakan naa lawọn gomina ọhun fẹnu ko pẹlu Aarẹ Buhari lati paarọ awọn ipo naa laarin iha Guusu ati Ariwa ilẹ wa, ati pe ko si ija tabi iyapa kankan laarin awọn gomina ẹgbẹ naa lori ọrọ yii, bo tilẹ jẹ pe aigbọra-ẹni-ye le ṣẹlẹ laarin awọn.
Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, lo ṣiṣọ loju eegun ọrọ yii lorukọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ lẹyin ipade wọn ọhun to waye nile ijọba, niluu Abuja, lọjọ Iṣẹgun.
O ni: “Lẹyin ipade ta a ṣe lalẹ ana (ọjọ Tusidee), a ti gba lati lo ilana pinpin ipo laarin awọn agbegbe mẹfa ti ilẹ wa pin si. Ni pato, awọn ipo to ti bọ sọwọ awọn eeyan agbegbe Ariwa lọdun mẹjọ sẹyin yoo lọ sọdọ awọn eeyan agbegbe Guusu lọtẹ yii, bẹẹ la si maa ṣe si awọn ipo to ti wa ni iha Guusu tẹlẹ.
“Ko ruju, ko si nira rara, eto naa ba ilana pin-in-ire la-a-ire mu ati aiṣojooro mu. Ni bayii, a maa lọọ jokoo, onikaluku maa pada sagbegbe rẹ lati fori kori, a maa wo awọn ipo to wa, eto apero gbogbogboo ẹgbẹ wa yoo si bẹrẹ lai sọsẹ.
“Tori naa, lagbara Ọlọrun, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ipade gbogbogboo ẹgbẹ wa maa waye, o si maa pari.
“Ṣẹ ẹ ri i, ko si bi gomina mejilelogun yoo ṣe sun ti wọn yoo si kọri sibi kan naa lori gbogbo ọrọ. A le ni aigbọra-ẹni-ye ati iyatọ diẹdiẹ, ṣugbọn iyẹn ko tumọ si pe a yapa si ara wa, ko le to’yẹn rara.
“Mo fi da yin loju pe awa gomina ta a nifẹẹ itẹsiwaju wa niṣọkan laarin ara wa, a si ti pinnu pe a o ni i jẹ kawọn araabi, awọn ẹgbẹ onimadaru ti wọn n pera wọn ni PDP yẹn pada sori aleefa rara.”