Lẹyin oṣu meji, wọn da awọn ọmọleewe Kaduna ti wọn ji gbe silẹ

Faith Adebọla

Aja to re’le ẹkun to bọ, ka ki i ku ewu ni, lẹyin to ku ọjọ mẹrin ki oṣu meji pe tawọn ọmọ naa ti wa lahaamọ awọn janduku agbebọn to ji wọn gbe, wọn ti da awọn ọmọleewe ijọba Federal College of Forestry Mechanisation, to wa lagbegbe Afaka, nipinlẹ Kaduna, silẹ.

ALAROYE gbọ pe nnkan bii aago meji ọsan Ọjọruu, Wẹsidee yii, ni wọn yọnda awọn ọmọ naa fawọn ti wọn lọọ gba wọn jade ninu igbo ọdaju ti wọn ha wọn mọ lati ọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun yii.

Mallam Abdullahi Usman, alaga awọn obi awọn ọmọ ileewe naa, lo ṣaaju ikọ ti wọn fa awọn ọmọ naa le lọwọ, lati inu igbo ti wọn ti lọọ gba wọn, wọn si ti ko wọn lọ siluu Kaduna fun itọju loju-ẹsẹ.

Wọn lọkunrin naa sọ fawọn oniroyin pe ọpẹlọpẹ gbajugbaja aṣaaju ẹsin Musulumi l’Oke-Ọya nni, Sheik Ahmed Gumi, wọn loun lo ṣeto bawọn ọmọ yii ṣe dẹni ominira.

Tẹ o ba gbagbe, mẹtadinlogoji lawọn akẹkọọ kọlẹẹji ọhun tawọn agbebọn ji gbe, ṣugbọn lẹyin ti wọn gba owo irapada ni wọn tu mẹwaa lara wọn silẹ, ti awọn mẹtadinlogbọn ti wọn ṣẹṣẹ dẹni ominira yii fi wa lakata wọn.

Pẹlu omije ati ẹdun ọkan lawọn obi awọn akẹkọọ yii fi lọọ ṣe iwọde nileegbimọ aṣofin apapọ ilẹ wa l’Abuja lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lati fi ibanujẹ wọn han, ti wọn si bẹ awọn aṣofin naa lati ma ṣe wo awọn niran lori ọrọ yii.

A o ti i le sọ boya awọn agbebọn yii gba owo, ati iye owo ti wọn gba, ki wọn too tu wọn silẹ.

CAPTION 

Leave a Reply