Stephen Ajagbe, Ilorin
Lẹyin ọdun kan ati oṣu mẹrin ti wọn lo ti sa lọ, ọwọ ọlọpaa pada tẹ Akinọla Babatunde, ọkan lara awọn afurasi to da ilu Odo-Ọwa atawọn ilu to wa lagbegbe rẹ ru, nibi ti eeyan mẹta ti padanu ẹmi wọn, o si ti dero ahaamọ bayii.
Akinọla tawọn eeyan mọ si Agoro lawọn ọlọpaa wọ wa sile-ẹjọ Magisreeti kan niluu Ilọrin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ile-ẹjọ si ti paṣẹ ko wa lahaamọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, CID.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o lọwọ ninu akọlu to waye lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹta, ati ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹrin, ọdun 2019, ninu eyi ti eeyan mẹta; Emmanuel Akinọla, Sunday Olukosi ati Ọlasunkanmi Agboọla ti padanu ẹmi wọn.
Afurasi ọhun pẹlu awọn mẹsan-an kan to n jẹjọ nile-ẹjọ giga tilu Ilọrin lori iṣẹlẹ naa, ninu eyi ti Oguntoye Bayọ wa lara wọn lawọn ọlọpaa fẹsun kan pe wọn gbe ohun ija oloro, oogun lati da ilu ru, eyi to yọri si iku awọn eeyan kan.
Olujẹjọ to jẹ ọmọ bibi agboole Arin-rin, niluu Odo-Ọwa, naa ni wọn fẹsun kan pe o ko ipa nla ninu akọlu ọhun, nigba to ri i pe awọn ọlọpaa n wa oun lo sa kuro niluu.
Agbẹjọro ijọba, Sgt. Isa Amọtẹkun, rọ ile-ẹjọ lati gbe olujẹjọ naa sahaamọ ọgba ẹwọn nitori pe iwadii ṣi n tẹsiwaju.
O ni oun ti fi iwe ẹsun naa ranṣẹ si ẹka to n gba ile-ẹjọ nimọran nileeṣẹ eto idajọ fun imọran lori ẹjọ naa.
Ṣugbọn agbẹjọro olujẹjọ, Ọgbẹni O.M Odeh ati Adelokun Adeoye, rọ ile-ẹjọ lati gba oniduuro onibaara wọn nitori pe o ti pẹ ju lahaamọ awọn ọlọpaa.
Adajọ Ọlaolu M Abayọmi ni ile-ẹjọ oun ko lagbara ati aṣẹ lati gbọ ẹjọ naa.
O gba ẹbẹ agbefọba naa wọle pẹlu bo ṣe paṣẹ pe ki wọn gbe olujẹjọ naa lọ sahaamọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ.
O sun ẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii