Lẹyin ọdun meje lakata Boko Haham, ọmọọleewe Chibok kan pada de pẹlu ọmọ meji to ti bi lọhun-un

Bi ẹmi ba wa, ireti o pin, lowe to wọ ọrọ Ruth Pogu, ọkan lara awọn ọmọbinrin ileewe Chibok tawọn Boko Haram ji gbe lọdun meje sẹyin. Ọmọ naa ti pada wale, wọn si ti fa a le awọn obi rẹ lọwọ, ṣugbọn oun pẹlu ọmọ meji to bi sọhun-un ni wọn jọ de.

Gomina ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Babagana Zulum, lo fa Ruth le awọn obi rẹ lọwọ lọjọ Satide, nile ijọba ipinlẹ ọhun to wa niluu Maiduguri.

Ba a ṣe gbọ, wọn ni aarin ọsẹ to kọja lọhun-un lọmọbinrin naa ati ẹni to bimọ fun ṣadeede wọlu wẹrẹ, lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje, pẹlu ọmọ meji ti wọn bi, ọwọ awọn ọmoogun ilẹ wa to n ṣiṣẹ aabo tọsan-an toru lagbegbe Bama ni wọn bọ si, wọn si ko wọn lọ sọfiisi wọn.

A gbọ pe ọkunrin Boko Haram ti wọn forukọ bo laṣiiri naa jẹwọ pe loootọ loun jẹ ọkan lara awọn afẹmiṣofo eeṣin-o-kọku Boko Haram to ti n fooro ẹmi awọn araalu lagbegbe naa, ṣugbọn ni bayii, oun ti tuuba ni toun, oun o ṣe mọ, oun ti ronu piwa da, oun si ṣetan lati sọrẹnda funjọba.

Bonkẹlẹ ni wọn ṣe ọrọ ọhun, niṣe ni wọn kọkọ bẹrẹ si i kan sawọn obi ọmọbinrin naa, pe ki wọn waa wo o boya ọmọbinrin wọn lo de loootọ. Lẹyin ti wọn ti fidi ẹ mulẹ pe ọmọ wọn ni, ọkan lara awọn akẹkọọ igba (200), tileewe Government Secondary School, Chibok, tawọn Boko Haram ji ko wọgbọ lọdun 2014 ni, ni wọn bẹrẹ si i fun ọmọbinrin naa atawọn ọmọ rẹ mejeeji ni itọju iṣegun, ki wọn too le fa a fawọn obi rẹ.

Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Borno, Mallam Isa Gusau, sọ pe inu gomina naa dun gidi lori iṣẹlẹ yii, o ni niṣe lọrọ naa tun mu ireti ijọba, araalu ati awọn obi tawọn ọmọ wọn ṣi wa lakata awọn Boko Haram sọ ji, pe lọjọ kan, ohun to lọ aa pada bọ, wọn aa tun ri ọmọ wọn gba pada, ayọ wọn aa si kun.

Bakan naa lo ni ijọba maa ṣeto gidi lati jẹ ki ilera ati idalẹkọọ akanṣe wa fun Ruth, tori ohun toju rẹ ti ri lahaamọ awọn ọdaran ẹda naa ti yatọ si ti araalu, ati pe awọn maa pese aabo to peye fun un kawọn araalu ma baa dẹyẹ si i, ki wọn maa fi i ṣẹsin-in tabi sa fun un.

Ni ti ‘ọkọ’ rẹ to loun ti ronupiwada, wọn lọkunrin naa ṣi maa wa lakata awọn ọmọ ogun ilẹ wa, lati bojuto ọrọ rẹ.

O nijọba ati ileeṣẹ ologun ko ni i kaaarẹ lati ri i pe awọn gba gbogbo ọmọleewe ataraalu to wa lakata awọn janduku ẹda naa pada laaye.

Leave a Reply