Faith Adebọla
Meji ninu awọn akẹkọọ-binrin rẹpẹtẹ ti ileewe Government Secondary School, to wa niluu Chibok, tawọn eeṣin-o-kọku afẹmiṣofo Boko Haram ji ko lati bii ọdun mẹsan-an sẹyin ti raaye sa asala fẹmi wọn kuro ninu igbo Sambisa, nipinlẹ Borno, ti wọn ha wọn mọ.
Alaroye gbọ pe awọn ọdọmọbinrin meji ọhun, ti wọn porukọ wọn ni Hauwa Mutah ati Esther Markus, ribi yọ pọrọ mọ awọn ajinigbe ti naa lọwọ loru ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin yii, ti wọn si dọgbọn rin irinajo gigun ninu okunkun, ninu igbo Sambisa ọhun ki Ọlọrun too ba wọn ṣe e ti wọn ribi jade si gbangba.
Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ alaabo to mọ si iṣẹlẹ yii, amọ ti ko fẹ ka darukọ oun fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni, o nigba ti wọn jade ninu igbo naa lawọn ṣọja ti wọn n ṣọ gbogbo agbegbe ọhun ri wọn, ti wọn si doola ẹmi wọn.
Onitọhun ni: “Awọn ọdọmọbinrin meji lara awọn akẹkọọ-binrin naa lori ko yọ lakata awọn Boko Haram. Ọkan wa lati ilu Chibok, ekeji si jẹ ọmọ abule Dzilang.
“Ninu awọn ọrinlerugba din mẹrin (276) akẹkọọ-binrin ti wọn ji ko nileewe ijọba to wa ni Chibok, awọn mẹtadinlọgọta ni wọn ribi sa lọ mawọn ajinjigbe naa lọwọ lọdun 2014, awọn Boko Haram funra wọn tu mẹtadinlaaadọfa (107) silẹ lọdun 2018. Ọdọbinrin mẹta la ri gba pada lọdun 2019, a ri meji gba pada lọdun 2021, a si tun ri mẹsan-an lọdun 2022. Aropọ gbogbo awọn ti wọn ti kuro lahaamọ bayii jẹ mejidinlọgọsan-an (178), o ṣi ku akẹkọọ-binrin mejidinlọgọrun londe awọn Boko Haram yii,” gẹgẹ bo ṣe wi.
Ẹ o ranti pe ọjọ kẹrinla oṣu Kẹrin, ọdun 2014 ni iroyin ibanujẹ naa gbode pe awọn ikọ mujẹmujẹ Boko Haram ya bo ileewe Government Secondary School to wa niluu Chibok ta a n sọrọ rẹ yii, nipinlẹ Borno, ti wọn si ji awọn akẹkọọ-binrin to din diẹ lọọọdunrun gbe wọgbo lọ.
Latigba naa ni ijọba, awọn ẹṣọ alaabo ileeṣẹ ologun ti ṣagbekalẹ oriṣiiriṣii ikọ alajumọṣe awọn jagun-jagun, eyi ti wọn pe ni Joint Task Force, lati doola ẹmi awọn ọmọleewe ọhun.
Laipẹ yii ni olori ẹka ọtẹlẹmuyẹ ikọ ologun ti wọn pe ni Hadin Kai, Kọnẹẹli Obinna Ezuipke, fidi ẹ mulẹ pe akẹkọọ-binrin bii mejidinlọgọrun-un lo ṣi ṣẹku sakata awọn Boko Haram, o lawọn o si dawọ isapa awọn duro lati ri gbogbo wọn gba pada, laaye.