Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọwọ ọlọpaa ti ba ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta kan, Adeyẹmi Adeọla, lori ẹsun pe o lu ẹnikan ni jibiti ẹgbẹrun lọna ọtalelọọọdunrun naira o din mẹwaa (#350,000)
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Ọlọkọde, sọ lasiko to n ṣafihan Adeyẹmi niluu Oṣogbo pe lati oṣu kẹsan-an, ọdun 2019, ni afurasi ti huwa naa.
Ọlọkọde ṣalaye pe ṣe ni Adeyẹmi gba owo naa lọwọ ẹnikan lati fi ba ọmọ rẹ wa ọna si ile-ẹkọ giga ati lati san awọn owo kekeke mi-in to nilo lati san to ba ti wọ ile-ẹkọ.
Ṣugbọn latigba naa ni wọn ko ti gburoo afurasi naa mọ. Nigba to su ẹni naa lo kọwe ẹsun lọ sọdọ awọn ọlọpaa lati ba a fi pampẹ ọba gbe e nibikibi to ba wọle si.
Bayii lawọn agbofinro bẹrẹ iwadii to lagbara lori Adeyẹmi titi ti wọn fi mọ ibi to sa lọ, ti wọn si lọọ gbe e nibẹ, ko si pẹ rara to fi jẹwọ pe loootọ loun gba owo naa.
Ọlọkọde sọ pe bi awọn ba ti pari gbogbo iwadii to yẹ lori ọrọ rẹ ni yoo foju bale-ẹjọ lati le jẹ ẹkọ fun awọn ti wọn tun ni iru ero bẹẹ lọkan.