Faith Adebọla, Eko
Pampẹ ti ajọ to n gbogun ti lilo, gbigbe ati ṣiṣe okoowo egboogi oloro nilẹ wa, NDLEA, dẹ re, o si mu Chidi Olife. Ọdun kẹwaa ree ti wọn ni afurasi ọdaran naa ti sa mọ ajọ NDLEA lọwọ tori egboogi oloro, idi okoowo buruku naa ni wọn tun ti mu un lọjọ Abamẹta, Satide yii, niluu Eko.
Atẹjade kan latọwọ ajọ ọhun nipa iṣẹlẹ yii sọ pe ọdun 2010 ni wọn ti kọkọ mu afurasi yii, ẹsun ti wọn fi kan an nigba naa ni pe o gbe egboogi oloro (Heroine), tijọba ti fofin de kan wọle lati orileede Pakistan. Inu awọn iwe kan lo dọgbọn tọju rẹ si, egboogi naa si tẹwọn ju kilogiraamu marun-un lọ (5.250kg).
NDLEA ni bawọn ṣe bẹrẹ iṣẹ iwadii lori egboogi ti wọn ka mọ ọgbẹni naa lọwọ, ko sẹni to le sọ bo ṣe ṣẹlẹ, ṣadeede lo dawati, wọn o mọ bo ṣe sa lọ mọ awọn ọtẹlẹmuyẹ lọwọ.
Wọn ni latigba naa ni wọn ti n wa a, ṣugbọn ko sẹni to pade ẹ, ajọ naa si yan igbimọ amuṣẹya kan lati maa dọdẹ ẹ. Ọgbẹni Adeniyi Olumuyiwa to jẹ igbakeji ọga to n ri si egboogi oloro lẹbulẹbu lalaga igbimọ naa.
Igbimọ yii lo fura pe awọn kan ti n gbọna ẹyin lọọ ko awọn iwe ti afurasi naa fi ko egboogi oloro wọle ọhun ninu kọntena ti wọn tọju ẹ si. Lẹyin ti wọn fimu finlẹ, wọn lawọn ri i pe awọn kan ti wọn pera wọn ni ejẹnti to n ṣiṣẹ lawọn ẹnubode eti omi ni wọn, ọwọ ẹṣọ NDLEA si ba meji ninu wọn, Ọgbẹni Ọladimeji Ọladọtun ati Alaaji Idris Danjuma. Wọn lawọn mejeeji yii lo n to iwe bi wọn ṣe maa ri kọntena naa gbe kuro leti omi, aṣe afurasi ọdaran naa lo fori pamọ sibi kan, to bẹ wọn lọwẹ.
Mimu ti wọn mu awọn ejẹnti meji yii lo ṣatọna bi wọn ṣe ri ẹni ti orukọ ẹ wa lakọọlẹ pe oun lo ni kọntena ti egboogi oloro naa wa atawọn iwe ti wọn fi ko o si, Ọgbẹni Ningo Oke mu, lawọn agbofinro ba fi pampẹ ofin gbe oun naa.
Asẹyinwa asẹyinbọ, akara tu sepo, Oke jẹwọ pe oun gan-an kọ loun ni ẹru ofin, o ni afurasi ọdaran ti wọn ti n wa yii lo ran awọn niṣẹ, o si mu wọn de ile Chidi Olife to wa lagbegbe Ajao Estate, ni Isọlọ. Ibẹ ni wọn ti ri ọdaran to ti sa fọdun mẹwaa ọhun mu pada.
NDLEA lawọn tun ti bẹrẹ iwadii lori afurasi yii atawọn tọrọ kan, ko si ni i pẹ rara tawọn maa taari wọn lọ sile-ẹjọ, ki wọn le fimu kata ofin.