Lẹyin ọdun mọkanlelọgbọn, ile-ẹjọ ni Akadiri lọba Ọkinni

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Loootọ ni pe ori ti yoo dade, inu agogo idẹ lo ti n wa, eyi lo difa fun bi ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun ṣe fopin si wahala lori ẹni to jẹ ojulowo Ọlọkinni ti ilu Ọkinni, nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ, lẹyin ọdun mọkanlelọgbọn ti wọn ti wa lori ẹ.

Lati ọdun 1991 ni ọkunrin kan, Ọmọọba Aminu Ọlawale, ti ni aafin tiẹ gẹgẹ bii Ọlọkinni, nigba ti Ọba Akadiri Ọkanọla naa si ni aafin tiẹ ninu ilu kan naa, ti aṣẹ si n jade latinu aafin mejeeji, eleyii to si ti fi ọpọ igba da yanpọnyanrin silẹ.

Ohun to ṣẹlẹ ni pe ni kete ti Olojudo ti Ido-Ọṣun to jẹ ọba to laṣẹ lati fi Ọlọkinni jẹ nigba naa ti jawe oye le Ọba Akadiri lori ni Aminu Ọlawale ti mori le kootu, ti Onidaajọ Olowofoyeku si dajọ ninu idajọ to ni nọmba HOS/116/91 pe iyansipo naa ko bofin mu.

Bayii ni Ọba Akadiri gbe idajọ yii lọ sile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lọdun 2000, ti awọn Onidaajọ Mojeed Adekunle Ọwọade, Mohammed Ambi-Usi Danjuma ati James Sheu Ariyibi si fagi le idajọ Onidaajọ Olowofoyeku loṣu Kẹta, ọdun 2015. Idajọ naa lo da Ọba Akadiri pada gẹgẹ bii ojulowo Ọlọkinni ti ilu Ọkinni.

Bi ẹjọ yii ṣe n lọ lọwọ naa ni Ọba Akadiri naa wọ Aminu Ọlawale lọ sile-ẹjọ giga ilu Oṣogbo. Ninu ẹjọ naa, eyi to bẹrẹ lọdun 2005, ni Ọba Akadiri ti pe ijọba ipinlẹ Ọṣun lẹjọ pe wọn ko gbọdọ fi oju ọba wo Ọlawale, o si tun pe Ọmọọba Aminu Ọlawale lẹjọ pe ko gbọdọ pe ara rẹ ni Ọlọkinni mọ.

Bi Ọlawale ṣe duro bii ẹlẹrii fun ara rẹ naa ni Ọba Akadiri duro bii ẹlẹrii fun ara rẹ, ti awọn mejeeji si ko gbogbo iwe ti wọn le fi rojọ gbera wọn lẹsẹ kalẹ ni kootu. Awọn agbẹjọro mẹta; Sikiru Adewọye, O. Ige ati K. Ọmọkanye ni wọn duro fun olupẹjọ, nigba ti Deji Atoyebi duro fun olujẹjọ kin-in-ni ti i ṣe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Saliu Aliyu ati M. O. Rauf si duro fun olujẹjọ keji ti i ṣe Ọlawale Aminu.

Ninu idajọ rẹ, eyi to waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, Onidaajọ A. O. Oyebiyi sọ pe olupẹjọ to ti jẹ Ọlọkinni lati 1991; lasiko ati lẹyin idajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọru, lo lẹtọọ lati wa lori itẹ naa.

O ni Ọlawale Aminu to jẹ olujẹjọ keji ko le jẹ Ọlọkinni ti Ọkinni pẹlu idajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, nitori naa, pipe e ni Ọlọkinni ta ko ofin, ko si le duro laelae.

Adebiyi fi kun idajọ rẹ pe niwọn igba ti ko si ẹni to gbe ẹjọ miiran dide lẹyin idajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti ọdun 2015, idajọ Onidaajọ Olowofoyeku ko le sọ Ọlawale di Ọlọkinni rara.

Adajọ paṣẹ pe ijọba ipinlẹ Ọṣun to jẹ olujẹjọ kin-in-ni ko gbọdọ pe olujẹjọ keji, iyẹn Aminu Ọlawale, ni Ọlọkinni ti ilu Ọkinni laelae.

O ni ọkunrin naa ko gbọdọ pe ara rẹ ni Ọlọkinni mọ, bẹẹ ni ko gbọdọ lo awọn nnkan to ni akọle Ọlọkinni lara titi digba ti ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun yoo fi gbọ ẹjọ to ba gbe lọ.

Leave a Reply