Lẹyin ọjọ kẹka ti wọn n wa wọn, wọn ba oku akẹkọọ meji nihooho ni KWASU  

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, ni wọn ba oku ololufẹ meji kan, Tobilọba Daniel, ati ọrẹbinrin rẹ, Arẹwa Abayọmi, akẹkọọ ileewe giga Fasiti ipinlẹ Kwara, (KWASU) Malete, ninu yara ti wọn n gbe lẹyin ọjọ mẹta ti wọn ti n wa wọn.

ALAROYE gbọ pe ipele keji ni awọn akẹkọọ naa wa, ti wọn si n ṣe idanwo lọwọ lasiko ti iṣẹlẹ buruku yii waye.

Ọkan lara awọn ẹlẹgbẹ wọn to ba oniroyin wa sọrọ sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe majele ni awọn oloogbe yii jẹ tori pe lẹyin ọjọ kẹta ti wọn o ri wọn ninu yara ikẹkọọ lati lọọ ṣedanwo ni wọn wa wọn lọ si ibi ti wọn gba ile si nigboro, ti wọn si ba oku awọn mejeeji nihooho lẹyin ti wọn ja ilẹkun wọle tan.

Alukoro ileewe naa, Hajia Saeedat Aliyu, sọ pe awọn alaṣẹ ileewe KWASU ko ti i sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa.

 

Alukoro ọlọpaa ni Kwara, (SP) Ajayi Ọkasanmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o sọ pe ọlọpaa lo ran wọn lọwọ lati ja ilẹkun wọle nigba ti iṣẹlẹ naa de etiigbọ wọn, wọn si ti ko oku wọn lọ sileewosan ẹkọṣẹ Fasiti, Ilọrin (UITH), fun ayẹwo to peye lati le mọ iru iku to pa wọn.

Leave a Reply