Lẹyin ọjọ kẹta ti wọn pa aṣofin Rilwanu, agbebọn tun paayan mẹsan-an ni Kaduna

Faith Adebọla

Ijọba ipinlẹ Kaduna ti fidi ẹ mulẹ pe eeyan mẹsan-an lawọn janduku agbebọn tun fibọn ran lajo aremabọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, nipinlẹ Kaduna, bẹẹ ni wọn ṣe ọpọ araalu leṣe.

Kọmiṣanna feto aabo abẹle nipinlẹ ọhun, Ọgbẹni Samuel Aruwan, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede nirọlẹ ọjọ naa.

Aruwan ni ki i ṣe oju kan ṣoṣo niṣẹlẹ yii ti waye, kaakiri awọn agbegbe bii mẹta ni. Eeyan meta ni wọn pa ni adugbo Buruku-Udawa, lọna Kaduna si Birnin Gwari, nijọba ibilẹ Chikum, nigba tawọn agbebọn naa gbegi dina, ti wọn n wa awọn ọkọ duro, wọn si ṣe awọn meji leṣe gidi.

O ni bakan naa lawọn eeyan buruku naa ṣeku pa ẹni kan ni adugbo Yola-Kadi, nijọba ibilẹ Chikun kan naa, ẹnikan si fara pa.

Awọn afẹmiṣofo yii ni wọn ni wọn tun pa eeyan meji labule Sako, nijọba ibilẹ Zangon Kataf, awọn agbofinro si tun ri oku eeyan meji mi-in nilẹ lagbegbe Kurfi-Magamiya.

Ni Zaria, eeyan kan lo ku nigba tawọn eeyan keeyan yii ya bo abule Saye, nijọba ibilẹ Zaria.

Gomina Nasir El-Rufai ti fi aidunnu rẹ han sawọn iṣẹlẹ ipaniyan wọnyi, o ṣadura fawọn to ku naa, pẹlu ileri pe ijọba oun ko ni i kaaarẹ lati da sẹria fawọn ti ẹmi eeyan o jọ loju yii.

Tẹ o ba gbagbe, alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ kan naa yii lawọn ọdaju afẹmiṣofo ẹda yii yinbọn pa ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Kaduna kan, Ọgbẹni Rilwanu Gadagau. Ọkunrin naa wa lara awọn arinrin-ajo ti wọn ko sọwọ awọn agbebọn yii loju ọna Kaduna si Zaria, fun bii wakati meji ni wọn fi n yinbọn lakọlakọ lalẹ ọjọ naa, ti wọn si ṣe ọpọ eeyan leṣe.

Ọjọ Wẹsidee ni wọn too ri oku aṣofin naa lẹgbẹẹ igbo, nitosi abule Mawai, nibi to japoro ku si, wọn si sin oku rẹ nilana ẹsin Musulumi lọjọ keji.

El-Rufai tun parọwa sawọn ologun lati tubọ pese aabo fawọn eeyan ipinlẹ naa.

Leave a Reply