Gbenga Amos
Niṣe lẹjẹ n ṣan bii omi lafẹmọju ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta yii, nijọba ibilẹ Giwa, nipinlẹ Kaduna. Abule mẹsan-an lawọn janduku afẹmiṣofo ṣakọlu si, wọn si ṣeku pe eeyan aadọta nibẹ.
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọjọ mẹrin tawọn janduku agbebọn naa da ẹmi eeyan marundinlogoji legbodo loru mọju ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ kan naa.
Yatọ si ifẹmiṣofo, niṣe ni wọn tun dana sun awọn ile, dukia, ọkọ ayọkẹlẹ, awọn ọkada, ẹrọ ati kẹkẹ ti wọn ba lawọn ileto naa, gbogbo ọja to wa ninu awọn ṣọọbu, ati ounjẹ tawọn oloogbe naa tọju, wọn si ji maaluu bii ọgọrun-un gbe.
Ọkan ninu awọn ẹṣọ fijilante to n ṣiṣẹ lagbegbe naa, Ọgbẹni Mansur Ibrahim, sọ fun ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe awọn ileto ti wọn ṣakọlu si ni Dillalai, Zango Tama, Kaya, Barebari, Anguwan Bakko, Gidan Alhajin Kida, Kadanya ati Durumi.
O ni Dillalai ni awọn agbebọn naa ti ṣoro ju lọ lasiko akọlu naa, tori eeyan bii mẹẹẹdogun ni wọn pa, wọn dana sun ọkọ akẹru marun-un, ile marun-un, wọn tun sun ṣọọṣi kan ni Zangon Tama.
O ni wọn ti gbe awọn ti wọn fara gbọgbẹ lasiko akọlu naa lọ si Ọsibitu Fasiti Ahmadu Bello, niluu Zaria.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Kaduna, Mohammed Jalinge, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, bo tilẹ jẹ pe o lawọn o le sọ pato iye eeyan ti wọn pa, o lawọn ṣi n reti ipe latọdọ DPO agbegbe naa ati Eria Kọmanda wọn.