Stephen Ajagbe, Ilọrin
Lẹyin ọjọ mẹrin ti wọn ti n wa Abdulwaheed Abdullateef, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ọjọ Abamẹta, (Satide), ana nileeṣẹ panapana ri oku rẹ ninu odo Moro, lagbegbe Oko-Olowo, niluu Ilọrin.
Atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ naa, Hassan Hakeem Adekunle, gbe sita, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mejila aabọ ọsan ọjọ naa lawọn lọọ wọ oku ọkunrin naa jade.
O ṣalaye pe ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Ọgbẹni Hassan lo ri oku naa nibi to le tente si leti odo naa, oun lo si fi to ileeṣẹ awọn leti.
Adekunle ni awọn ti yọnda oku rẹ fawọn mọlẹbi rẹ.
O waa gbadura ki Ọlọrun tu awọn ẹbi rẹ ninu.