Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti pa a ti, atunṣe bẹrẹ loju ọna Oṣogbo, Iwo si Ibadan

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Iroyin ayọ lo jẹ fun gbogbo awọn arinrin-ajo loju ọna Oṣogbo si Iwo kọja si Ibadan, nigba ti wọn gbọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe iṣẹ atunṣe yoo bẹrẹ nibẹ lọgan.

Bẹẹ naa ni kọngila to gba iṣẹ oju-ọna, Peculiar Consult and Peculiar Ultimate Concerns Ltd, Ẹnjinnia Lanre Adeleke, ṣeleri pe iṣẹ atunṣe oju ọna ọhun yoo pari, o pẹ tan, laarin oṣu mejidinlogun ti i ṣe ọdun kan aabọ.

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, ṣalaye pe idunnu nla ni iṣẹ atunṣe naa jẹ fun oun nitori yoo mu ki eto ọrọ-aje agbegbe naa rugọgọ si i, ti yoo si mu ki awọn ti wọn ti pa oju ọna naa ti pada sibẹ.

Ọba Akanbi, ẹni ti ogunlọgọ awọn ori-ade lati agbegbe Iwo ba kọwọọrin lọ si oju-ọna naa, sọ siwaju pe inira nla ni oju-ọna ti mu ba awọn eeyan oun lati ọpọ ọdun sẹyin, ti ko ti si ijọba to fọwọ kan an.

O ni iwuri nla lo jẹ fun oun pe Gomina ipinlẹ Ọyọ, Enjinnia Ṣeyi Makinde, ati ti Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, le pa ẹgbẹ oṣelu ti, ki wọn si fẹnu ko lati jumọ ṣe iṣẹ oju ọna ọhun.

Ọba Akanbi fi kun ọrọ rẹ pe iṣẹ naa yoo tubọ mu ki ifọwọsowọpọ to lọọrin tubọ wa laarin awọn ipinlẹ mejeeji, ti itura yoo si ba awọn eeyan agbegbe naa.

Ẹnjinnia Adeleke ṣeleri nibẹ pe dipo bii wakati meji ti awọn arinrin-ajo fi n rin oju-ọna Ibadan si Oṣogbo tẹlẹ, irin naa ko ni i ju aadọta iṣẹju lọ mọ ti iṣẹ atunṣe naa ba ti pari.

O waa rọ awọn awakọ lati ṣe ṣuuru lasiko iṣẹ naa, o ni awọn ti n gbe oniruuru igbesẹ lati pese awọn ọna ti yoo wa fungba diẹ fun wọn titi digba ti iṣẹ atunṣe naa yoo fi pari.

Leave a Reply