Lẹyin ọsẹ meji ti Basiru jajabọ lọwọ awọn ajinigbe lo ku

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan ninu awọn mẹrin ti awọn agbebọn ji gbe loju ọna marosẹ Ọwọ si Akungba- Akoko, Basiru Adekilẹ, pada ku lẹyin bii ọsẹ meji to ti jajabọ lọwọ awọn to ji wọn gbe.

Basiru, Oniku ti Iku, niluu Ikarẹ Akoko, Oloye Giga Mukaila Bello atawọn meji mi-in lawọn agbebọn ọhun da lọna ninu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla ti wọn wa lasiko ti wọn kọja Ọwọ diẹ, ti wọn si ko awọn mẹrẹẹrin wọ inu igbo lọ.

Bo tilẹ jẹ pe ọwọ awọn ẹsọ Amọtẹkun pada tẹ diẹ ninu awọn ajinigbe ọhun lẹyin-ọ-rẹyin, wọn ti kọkọ gba owo to to miliọnu mẹta Naira lọwọ wọn ki wọn too yọnda wọn ninu igbekun ti wọn de wọn mọ.

Basiru ni wọn ni ko fi bẹẹ gbadun mọ rara latigba ti wọn ti tu wọn silẹ latari iya nla to jẹ lasiko ti wọn fi wa ni ikawọ awọn to ji wọn gbe.

Lati bii ọsẹ meji sẹyin lo si ti n ti ile-iwosan kan bọ si omiiran fun itọju, ṣugbọn ti ọrọ naa pada ja si iku fun un l’Ọjọbọ, Tọsidee

Leave a Reply