Lẹyin tawọn ọrẹ mẹta rọ Adewumi lọti yo ni wọn ba fipa ba a lo pọ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn ọrẹ mẹta ti wọn fẹsun kan pe wọn fipa ba ọmọbinrin kan, Ogungbemi Adewumi lo pọ lẹyin ti wọn ti rọ ọ lọti yo niluu Ondo.

Awọn afurasi mẹtẹẹta, Ojo Ọlaniyi, Akinṣẹyẹ Bayọ ati Akintọsoye Ayọ la gbọ pe wọn fi ọgbọn tan ọmọbinrin naa lọ si ile kan laduugbo Ararọmi, nibi ti wọn ti kọkọ fun un lọti mu yo, ki wọn too maa ba a lo pọ lọkọọkan.

Ẹnikan to jẹ ẹgbọn Adewumi la gbọ pe o ka awọn afipabanilopọ naa mọ’bi ti wọn ti n ṣe kinni ọhun lọwọ, to si lọọ fẹjọ wọn sun lagọọ ọlọpaa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Bọlaji Salami, ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan Ojo atawọn ọrẹ rẹ yooku.

O ni lọgan ti iwadii awọn ba ti pari lawọn yoo ko wọn lọ sile-ẹjọ lati lọọ sọ tẹnu wọn niwaju adajọ.



Leave a Reply