Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Onimọ-ẹrọ Ayọ Alabi pẹlu ẹgbọn rẹ ati awọn ati awọn mẹta miiran lawọn ajinigbe ji gbe laarin Oke-Onigbin si Omu-Aran, nijọba ibilẹ Isin, nipinlẹ Kwara, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu kẹjọ, ọdun yii, lakoko ti wọn n dari bọ lati ibi ayẹyẹ kan ni Osi Ekiti si Ilọrin. Wọn si n bere fun ọgbọn miliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ, sugbọn awọn mọlẹbi tiraka, wọn san miliọnu mẹrin ataabọ fun idoola ẹmi ọkunrin na lẹyin ọpọlọpọ idunaadura.
ALAROYE gbọ pe nigba ti wọn yoo fi tu baba agbalagba yii silẹ, wọn ti lu u bii kiku bii yiye, wọn ti sọ ọkunrin na di idakuda debii pe ko le rin, bẹẹ ni ko le da duro. Ọkada la gbọ pe wọn fi gbe e jade kuro ninu igbo naa, ti wọn si gbe e taara lọ si ileewosan.
Ni nnkan bii aago mẹrin aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ ta a lo tan yii, ni wọn ni ọkunrin naa dakẹ nileewosan ọhun.