Ọmọleewe Chibok mi-in tun jajabọ lọwọ awọn Boko Haram, ọmọ meji loun naa ti bi sọhun-un

Faith Adebọla

Lẹyin ọsẹ kan ti wọn fa Ruth Poga ati awọn ọmọ meji to ti bi fawọn afẹmiṣofo le awọn obi rẹ lọwọ, ọmọleewe Chibok mi-in, Hassan Adamu, tun raaye jajabọ lọwọ awọn ajinigbe agbebọn naa, ọmọ meji loun naa ko de, awọn Boko Haram lo bimọ fun.

Ọjọ Abamẹta, Satide yii, ni awọn ṣọja kẹẹfin ọmọbinrin nibi to ti n fori jagbo bọ pẹlu awọn ọmọ rẹ mejeeji, ninu papa gbalasa Sambisa.

Ninu atẹjade kan ti Amugbalẹgbẹẹ feto iroyin Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum, fi lede, Ọgbẹni Isa Gusau sọ pe awọn ọmọọgun ti fa akẹkọọ-binrin to ti di iya aburo yii le Kọmanda 26 Task Force Brigade, Ọgagun D. R. Dantami, lọwọ, fun iwadii ati igbesẹ to yẹ, lẹyin naa ni wọn fa a le Gomina Zulum lọwọ.

Bakan naa lo ni awọn ti bẹrẹ si i ṣewadii lati mọ obi ọmọbinrin yii, ki wọn le waa wo o boya ọmọ wọn ni loootọ, ki wọn si le tete bẹrẹ itọju iṣegun to yẹ fun un.

Atẹjade naa ni ọjọ marun-un ni gomina ti fi wa pẹlu awọn ọmoogun ati awọn ogunlende lagbegbe ọhun, lati pese itọju, iṣiri ati iranwọ ounjẹ ati owo fun wọn.

Ẹ oo ranti pe lati ọjọ kẹrinla, oṣu kẹrin, ọdun 2014, lawọn eeṣin-o-kọ’ku Boko Haram ti ya bo ileewe ijọba Government Secondary School, to wa lagbegbe Chibok, nipinlẹ Borno, ti wọn si fipa ji awọn akẹkọọ-binrin okoodinlọọọdunrun o le mẹfa (276) gbe wọgbo lọ.

Latigba naa lawọn ọmọbinrin naa ti wa lakata wọn, bo tilẹ jẹ pe wọn ri awọn diẹ kan gba lara wọn lẹyin ọdun mẹrin. Ọpọ awọn ọmọ naa lawọn agbebọn Boko Haram ti fun loyun, ti wọn si ti bimọ, pẹlu igbeyawo afipaṣe ti wọn ṣe fun wọn lọhun-un, bo tilẹ jẹ pe ojoojumọ nijọba n ṣeleri pe awọn yoo ṣi ri awọn ọmọ ọhun gba pada to ba ya.

Leave a Reply