Lẹyin ti ijọba ṣe ohun ti wọn beere, awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ogun ti pada sẹnu iṣẹ o

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ Ogun ti fagi le iyanṣelodi ti wọn bẹrẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Igbesẹ yii waye lẹyin tawọn aṣoju ajọ oṣiṣẹ tọwọ bọwe adehun igbọra-ẹni-ye pẹlu ijọba lẹyin ipade mi-in ti wọn tun ṣe lọfiisi gomina l’Oke-Mosan lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Koda, ẹkunwo ti wọn ti ni inu oṣu kọkanla nijọba yoo bẹrẹ ẹ paapaa, oṣu kẹwaa to n bọ yii ni wọn yoo bẹrẹ si i san an bayii.

Lara awọn nnkan ti wọn fẹnu ko si ninu ipade naa ni :

Sisanwo oṣu ẹlẹgbẹrun lọna ọgbọn fun oṣiṣẹ to kere ju ti yoo bẹrẹ lati oṣu kẹwaa, ọdun 2020. Igbega fawọn to yẹ fun lati ọdun 2018 yoo bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ, owo ajẹmọnu ati wiwọ ọkọ BRT yoo bẹrẹ loṣu kin-in-ni, ọdun 2021.

Awọn to ṣoju ijọba nibi ipade yii ni: Olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun; Alaaji Salisu Shuaibu, Tokunbọ Talabi; Akọwe ijọba fun Gomina Dapọ Abiọdun ati Pasitọ Rẹmi Hazzan ti i ṣe oludamọran pataki fun gomina lori eto iroyin, nigba ti awọn olori awọn oṣiṣẹ naa ko gbẹyin pẹlu.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//unbeedrillom.com/4/4998019
%d bloggers like this: