Adewale Adeoye
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ yii, ‘Economic And Financial Crimes Commission’ (EFCC), ti foju awọn ọmọ Yahoo meji kan, Raheem James ati Chisom Okoye, bale-ẹjọ giga kan nipinlẹ Kaduna, niwaju Onidaajọ A.A. Isiaka.
Ẹsun pe wọn n lo ẹrọ ayelujara fi ṣe gbaju-ẹ fawọn araalu, eyi ti wọn sọ pe, ofin orile-ede Naijiria fajuro si gidi, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ ni wọn fi kan awọn mejeeji yii.
Alukoro ajọ naa, ẹka tipinlẹ Kaduna, ṣalaye pe ilu Abuja tawọn ọdaran naa sa lọ lọwọ ti tẹ wọn, ko too wa di pe wọn fọwọ ofin mu wọn wa sipinlẹ Kaduna ti wọn ti ṣẹ ẹṣẹ naa.
ALAROYE gbọ pe oniruuru ẹrọ ayelujara lawọn ọdaran yii maa n lo lati fi ṣe gbaju-ẹ fawọn onibaara wọn, ti wọn aa si gba owo nla lọwọ wọn.
Loju-ẹsẹ ti wọn ti foju wọn bale-ẹjọ naa tan ni awọn mejeeji ti jẹwọ pe loootọ lawọn jẹbi gbogbo awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn, ṣugbọn ki adajọ ile-ẹjọ naa ṣiju aanu wo awọn.
Ọrọ tawọn olujẹjọ yii sọ lo mu ki ọlọpaa olupẹjọ, K.S Oganlade, fi rọ adajọ ile-ẹjọ naa pe ko fiya to tọ jẹ wọn, ko le jẹ ẹkọ nla fawọn yooku pe iwa jibiti ki i ṣohun to daa rara.
Onidaaajọ Isiaka sọ James sẹwọn ọdun meji pẹlu iṣẹ aṣekara, tabi ko san ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira gẹgẹ bii owo itanran.
Bakan naa ni wọn ni ko juwọ ọọdunrun dọla owo ilẹ okeere ti wọn gba lọwọ rẹ fun ijọba apapọ.
Ni ti Chisom, adajọ ni ko lọọ ṣẹwọn ọdun mẹta tabi ko san ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira gẹgẹ bii owo itanran. Bakan naa ni wọn sọ pe ko juwọ foonu Samsung Galaxy kan ti wọn gba lọwọ rẹ silẹ fawọn aláṣẹ ijọba apapọ.