Lẹyin ti Sunday Igboho ba kuro ni orileede Benne, a maa gbe e pada si Naijiria lati waa jẹjọ -Malami

Jọkẹ Amọri

Minisita fun eto idajọ nilẹ wa, Abubakar Malami, ti sọ pe ọna oṣelu ni awọn yoo fi yanju ọrọ ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Igboho, to wa ni orileede Olominira Benne, ti wọn ba gbe e pada de si Naijiria.

O ni Naijiria ni wọn yoo gbe Igboho wa lati waa jẹjọ rẹ lẹyin to ba pari eyi to n jẹ ni orileede Benne.

O sọrọ yii nigba to n sọrọ lori eto kan lori Channels Tẹlifiṣan ti wọn pe ni ‘Politics Today.’

O ni ẹjọ ti Igboho n jẹ lọwọ nilẹ Benne ni i ṣe pe pe o tẹ ofin ilẹ wọn loju.

Malami ni, ‘A maa faaye gba ofin orileede to kọkọ ru lati ṣe idajọ tiwọn labẹ ofin. Lẹyin ti wọn ba pari eleyii la maa gbe e pada wa si Naijiria lati waa jẹjọọ ofin to ru nibi yii naa. A ko da si igbẹjọ rẹ bo ṣe n lọ ni ilẹ okeere to wa.’’

Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja ni ijọba ilẹ Bẹnnẹ kede pe awọn ti fi oṣu mẹfa ku asiko ti Sunday Igboho yoo lo lẹwọn.  

Eyi yatọ patapata si ireti awọn ololufẹ gbajugbaja ajijangbara ọmọ ọhun pẹlu bi ọkan ninu awọn agbẹjọro rẹ, Amofin agba, Oloye Yọmi Aliu, ti fidi ẹ mulẹ pe ijọba orileede Benne ti fi oṣu mẹfa, o kere tan, kun asiko tọkunrin naa yoo fi wa lahaamọ wọn.

Ninu ọrọ kan ti Aliyu ba awọn oniroyin sọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu keji yii, o ni:

“Yatọ si ọrọ ti wọn n gbe kiri laipẹ yii pe lọọya kan sọ, ijọba orileede Olominira Benin ti ṣafikun si asiko ti Oloye Sunday Adeyẹmọ (Sunday Igboho) yoo fi wa lahaamọ wọn, oṣu mẹfa ni wọn fi kun un, bo tilẹ jẹ pe ko si ẹsun iwa ọdaran kan ti wọn ka si i lẹsẹ niluu Kutọnu, bẹẹ ni ko si iwe ibeere lati da a pada sile kankan latọdọ ijọba Naijiria.”

Amofin agba naa tun ṣalaye pe onibaara oun ti pinnu lati ko ẹjọ rẹ lọ sọdọ ile-ẹjọ agbaye ti ajọ olokoowo Iwọ-Oorun Afrika, lati ba wọn da sọrọ naa, tori aiṣedajọ ododo ati iwa ifiyajẹni lainidii nijọba orileede Bẹnẹ n hu, pẹlu bi wọn ṣe n fi itusilẹ rẹ falẹ.

Ṣe ọkan ninu aọn agbẹjọro Sunday Igboho to gba awọn ọmọ rẹ ti awọn ọtẹlẹmuyẹ ko lọjọsi silẹ nile-ẹjọ, Ọgbẹni Pẹlumi Ọlajẹngbesi sọ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un to ṣaaju, nibi to ti sọ pe ireti to daju wa pe Sunday Igboho yoo kuro lahaamọ ẹwọn orileede Olominira Benin ti wọn ti i mọ, yoo si dẹni ominira laipẹ.

Ohun ti Ọlajẹngbesi kọ sori opo ayelujara Fesibuuku rẹ, eyi to ti n mu ki inu awọn ololufẹ ọkunrin naa dun ni pe: “Oloye Sunday Igboho yoo jade laipẹ, iro ayọ ati idunnu yoo si sọ kaakiri ilẹ Yoruba pata. Ko si iyemeji nibẹ pe akikanju ọkunrin gidi ni.”

Ọlajẹngbesi tun fi kun un pe: “Ọrọ to fidi mulẹ daadaa ni mo n sọ o, o kan jẹ pe awọn aṣaaju ilẹ Yoruba wa yii gbọdọ lọọ wa ọwọ iwa abosi, imọtara-ẹni-nikan, bọlẹ, ki wọn si gbe ki iwa rere, leke.”

 Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu kẹfa, ọdun to kọja ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa, DSS, ya lọ si ile Igboho to wa niluu Ibadan, nibi ti wọn ti pa ọmọọṣẹ rẹ meji, ti wọn ba ile rẹ jẹ, ti wọn si ko ọpọlọpọ nnkan lọ nibẹ. Ẹsun ti awọn ọtẹlẹmuyẹ yii fi kan an ni pe o n ko ohun ija oloro pamọ, o si n gbiyanju lati da alaafia ilu ru.

Sunday Igboho nipasẹ Agbẹjọro rẹ, Oloye Yọmi Aliu ti gbe ọrọ yii lọ sile-ẹjọ niluu Ibadan, adajọ si ti sọ pe ajijagbara yii ko ni ẹṣẹ kankan, bẹẹ lo ni ki ijọba san owo nla fun un fun pe wọn ba dukai rẹ jẹ.

Ṣugbọn nibi tọrọ de duro yii, o ṣee ṣe ki wọn gbe Sunday Igboho pada si Naijiria.

Leave a Reply