Faith Adebọla
Ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Abuja ti wa egbo dẹkun fun ogbologboo olokoowo egboogi oloro gbigbe meji kan, Ọgbẹni Christian Ikenna Uwaezuoke ati Ọmọọba Chidike Agbo, niṣe ladajọ diju mọri ṣedajọ fun wọn, to ni ki wọn lọọ lo iyooku igbesi aye wọn lọgba ẹwọn, keyii le jẹ ẹkọ fun wọn pe jijingiri ninu iwa irufin ko lere, niṣe ni i ko ba ni.
Alukoro ajọ to n gbogun ti lilo, gbigbe, mimu, jijẹ, ati ṣiṣe okoowo egboogi oloro nilẹ wa, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin yii.
O ṣalaye bawọn afurasi yii ṣe bẹrẹ irinajo arufin wọn nidii okoowo egboogi oloro gbigbe, ki wọn too pari ẹ sọgba ẹwọn gbere.
O ni lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022, lọwọ NDLEA tẹ Uwaezuoke, ẹni ọdun mẹtalelogoji ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe, l’Abuja, nigba ti aṣiri tu pe niṣe lo gbe egboogi oloro ti wọn n pe ni kokeeni (cocaine) ti iwọn rẹ le ni kilogiraamu meji (2.243kg) mi, lailọọnu kan ni wọn di wọn si lọna bii ọgọrun-un, ni wọn ba ni ko ‘ṣu dundun’ o ya kinni naa mọgbẹẹ, ti wọn si mu un.
Wọn foju rẹ bale-ẹjọ lẹyin iwadii, o loun ko jẹbi pẹlu alaye, lọọya rẹ si bẹbẹ fun beeli, nile-ẹjọ ba yọnda ki wọn gba beeli rẹ. Amọ niṣe ni jagunlabi sa lọ, to si ko awọn oniduuro rẹ si yọọyọ.
Nigba to ya, kootu paṣẹ ki wọn kede rẹ bii afurasi ti wọn n wa, wọn si wọgi le beeli rẹ.
Babafẹmi ni iyalẹnu lo jẹ nigba tọwọ tun ba Uwaezuoke lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ, ọdun to kọja. Lọtẹ yii, papakọ ofurufu Murtala Mohammed, n’Ikẹja, niluu Eko, ni wọn ti mu un pẹlu egboogi oloro kokeeni to din diẹ ni kilogiraamu meji (1.822kg) to fẹẹ gbe sọda sorileede India. Wọn ni niṣe lo lọọ yi orukọ ẹ pada, Ilonzeh Kingsley Onyebuchi lo pe ara ẹ, kawọn agbofinro ma baa tete fura si i.
Nigba tọwọ ba ẹlẹgiri, wọn gbe e lọ ile-ẹjọ kan l’Ekoo, niwaju Onidaajọ Nicholas Oweibo. O jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun meji ti wọn fi kan an, adajọ si dajọ lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 ọhun pe ko lọọ faṣọ penpe roko ọba lẹwọn fun ọdun meje, tabi ko sanwo itanran miliọnu kan aabọ Naira. O loun maa sanwo itanran ni, o si san an, ẹyin eyi ni wọn taari rẹ siluu Abuja, o di iwaju Adajọ Abilekọ Joyce Obechi Abdulmalik.
Lọtẹ yii ẹwẹ, o loun gba pe oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, o loun ko ni i ṣe bẹẹ mọ, ki kootu ṣaaanu oun, amọ adajọ naa ni oun ko ri apẹẹrẹ ironupiwada kankan lara afurasi ọdaran yii, o ni oju aye lasan lo n ṣe, iwa gbigbe egboogi oloro ti di baraku fun un, tori ẹ, o paṣẹ pe ko lọọ lo iyooku aye rẹ lẹwọn.
Ni ti ọrẹ rẹ, Ọmọọba Agbo Chidike, ẹni ọdun mejilelogoji, bii iro ni iborun ri lọrọ oun naa, papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe, l’Abuja, ni wọn ti mu un nibi to ti fẹẹ wọ baaluu Ethopian Airlines to n lọ sorileede Hong Kong, lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023. Ẹru egboogi oloro kokeeni ti wọn di sọna mọkandinlaaadọta lo ti gbe mi, o fẹẹ lọọ ya a mọgbẹẹ to ba debi to n lọ, amọ ọwọ tẹ ẹ.
Nigba ti wọn ṣewadii rẹ tan, ti wọn foju rẹ bale-ẹjọ giga apapọ kan, nibi ti Onidaajọ Joyce Obehi Abdumalik ti n da sẹria fawọn ọmọ alaigbọran, ẹsun kan ṣoṣo pere ni wọn ka si i lẹsẹ, wọn lo gbe kokeeni to tẹwọn to ẹgbẹrun kan giraamu (998.73g).
Ko si ẹbẹ ti agbẹjọro rẹ ko fẹrẹ bẹẹ ile-ẹjọ yii tan, bo ṣe n rawọ ẹbẹ, bẹẹ loo n parọwa pe ki wọn ṣiju aanu wo onibaara oun, o ni ko ṣe iru ẹ ri, ko si ni i ṣeru ẹ mọ, amọ Adajọ Abdulmalik ni oun gbọ ni, oun ko gba, o ni oun mọ owo gọbọi ti iba wọle sapo afurasi naa ka ni wọn ko ri i mu ni, ati akoba ti iba ṣe fun orileede yii, atawọn ti wọn n taja ofin fun, tori ẹ, o dajọ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii pe ki wọn maa wọ ọ lọ sọgba ẹwọn, ki wọn si sọ kọkọrọ ẹwọn naa nu sodo ti wọn ba ti ti i mọ’hun-un tan, lede mi-in, ẹwọn gbere ni wọn da foun naa.