Lẹ́yìn ti wọn gba mílíọ̀nù marun-un, wọn ti tu olori ilu Imọpẹ ti wọn ji gbe silẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Oloye TKO Ọmọtayọ, olori ilu Imọpẹ, tawọn kan jigbe lọjọ Satide to kọja yii ni Oke-Ẹri, Ijẹbu-Igbo, ti gba itusilẹ lọwọ awọn to ji i gbe naa.

Nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wọn yọnda ẹ, miliọnu marun-un naira la gbọ pe itusilẹ naa ba de.

Bi a ṣe n kọ iriyin yii lọwọ, ileewosan kan ni TKO ti wọn tun n pe ni Alademẹta, wa to ti n gba itọju.

 

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi ẹ mulẹ pe olori ilu Imọpẹ naa ti gba itusilẹ, o ni ṣugbọn oun ko mọ nnkan kan nipa pe wọn sanwo fawọn to ji i gbe tabi bẹẹ kọ.

Ẹ oo ranti pe Ijẹbu-Ode ni ọkunrin to jẹ aarẹ ẹgbẹ Ijẹbu Igbo club naa lọ lọjọ Satide to kọja, nigba to n pada bọ ni awọn agbebọn ti wọn ni Fulani ni wọn, da a lọna, ti wọn gbe e sa lọ. Wọn ko fọwọ kan mọto jiipu rẹ, Alademẹta nikan ni wọn gbe wọgbo lọ.

Miliọnu lọna igba la gbọ pe wọn lawọn yoo gba kawọn too tu u silẹ, ṣugbọn wọn ti pada yọnda rẹ bayii, lẹyin miliọnu marun-un ba a ṣe gbọ

Leave a Reply